Faith Adebọla, Eko
Bi wọn ba n sọ pe “Owuyẹ, aṣoro-i-sọ-bii-ọrọ” ati pe ‘ẹyin lohun, bo ba bọ silẹ, ko ṣee ṣa jọ mọ,’ iru ẹ ni ti ọrọ kan to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara bayii, eyi ti Alaga igbimọ to n ṣamojuto awọn ibudokọ ero nipinlẹ Eko, iyẹn Lagos State Parks Management Committee, Alaaji Musiliu Ayinde Akinsanya, tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ, sọ, nibi to ti n dunkooko mọ awọn oludibo kan tawọn eeyan gbagbọ pe awọn ẹya Igbo lo n ba wi. Ọkunrin naa ti jade sita bayii pe oun ko ba ẹnikẹni wi o, oun o si dunkooko mọ ẹnikẹni rara, o loun kan n fi ọwọ ṣere, oun n ṣẹfẹ ni toun ni, awọn eeyan ni wọn yi ọrọ oun pada, ti wọn ba oun tumọ ẹ sibi toun o rokan ẹ si.
Ninu fidio kan to gbe sori ikanni Insitagiraamu rẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta yii, iyẹn ọjọ keji to sọrọ to da awuyewuye silẹ ọhun, MC Oluọmọ ni oun ko ba ẹnikẹni wi ninu ọrọ toun sọ ti wọn n tọka si ọhun, o lawọn ati ẹya Igbo ti n ṣaṣepọ tipẹ, ẹfẹ lasan loun kan n fi ọrọ ṣe, ati pe Mama Chukwudi toun darukọ ẹ pe ti wọn o ba ti ni i dibo fun ẹgbẹ APC awọn, ki wọn ma wulẹ jade lọjọ idibo, ọrẹ oun tipẹtipẹ ni Mama Chukwudi yii, oun kan darukọ lati fi ṣawada ni.
O loun o tiẹ kọkọ mọ pe awọn kan ti gba ọrọ toun sọ ọhun bii ẹni gba igba ọti, afigba ti ọmọ oun kan fi fidio ṣọwọ soun lori ẹrọ ayelujara pẹlu oriṣiiriṣii esi ọrọ, eebu ati ọrọ kobakungbe tawọn eeyan n sọ nipa ẹ, ti wọn n tumọ ọrọ oun sibi to wu wọn.
MC Oluọmọ tun ni awọn alaboosi kan ni wọn fẹẹ yi ọrọ tawọn sọ bii ṣereṣere pada, ti wọn fẹ kawọn eeyan maa ri oun bii ẹni buruku. O ni ipinlẹ to lalaafia nipinlẹ Eko, awọn o si gbadura ki ogun ṣẹlẹ nibẹ.
Boun ṣe n sọrọ rẹ tan, ni Mama Chukwudi to jokoo sẹgbẹẹ rẹ fara han ninu fidio ọhun, mama agbalagba ọhun si tẹnu bọrọ pe lede adamọdi gẹẹsi, iyẹn pidgin pe MC Oluọmọ ko le maa fọrọ ranṣẹ sawọn ẹya Igbo, ko si le dunkooko mọ wọn, tori eeyan alaafia ni, ọmọluabi si ni, oun atiẹ ti jọ wa tipẹ.
Alaroye gbe iroyin yii jade ṣaaju pe MC Oluọmọ sọrọ to da awuyewuye silẹ yii l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta yii, nigba to n ba awọn alatilẹyin ẹgbẹ APC kan sọrọ nibi ipade aṣekagba eto ipolongo ibo kan, ninu gbọngan nla kan l’Ekoo.
Ninu fidio ati fọto to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara, MC Oluọmọ di ẹrọ abugbẹmu mu, ketekete si lohun rẹ jade bo ṣe n sọ pe:
“A ti bẹ yin, a ti rọ yin, emi dẹ tun fẹẹ bẹ yin ni, dandan kọ ni kẹ ẹ dibo fun wa, amọ tẹẹ ba ti mọ pe ẹ o ni i dibo fun wa, ki i ṣe ija. Ẹ sọ fun ara yin, Mama Chukwudi, tẹ ẹ o ba ti ni i dibo fun wa, ẹ jokoo sile yin. Ẹ jokoo sile yin o, ẹ ma jade,” ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bi MC Oluọmọ ṣe n sọrọ ọhun lawọn eeyan ti sọ pe ẹya Igbo lo n fọrọ ọhun dunkooko mọ, wọn si pe akiyesi awọn agbofinro si i, wọn ni ko yẹ ki wọn maa wo ọkunrin yii niran bẹẹ, wọn ni MC Oluọmọ ti fẹẹ sọ ara ẹ di ‘aṣẹ-ma-lu ẹran ọba’, ko si ṣeni to gbọdọ ga kọja ofin.