Ọlawale muti yo lọjọ idibo, nibi to ti n sa fọlọpaa lo ti lari mọ kọlufẹẹti

Faith Adebọla

Bi ko ba si ti kọnkere nla to duro bii kukute to wa lẹgbẹẹ titi, ti awakọ to porukọ ara ẹ ni Ọlawale yii fori mọto ẹ sọ ni, boya iba ti lokuu eeyan lọrun, iyẹn boun funra ẹ ko ba doloogbe, latari b’ọkunrin naa ṣe wa ọkọ niwakuwa lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta yii, lasiko ti eto idibo n lọ lọwọ nipinlẹ Eko, niṣe lo fori ọkọ naa sọ kọnkere ọhun, to si baye ọkọ ayọkẹlẹ bọginni naa jẹ laarin iṣẹju aaya.

Iṣẹlẹ yii waye ni nnkan bii aago kan ọsan ọjọ Satide, lagbegbe too-geeti atijọ to wa ni 7Up, nijọba ibilẹ Onidagbasoke Ikosi-Iṣheri, nipinlẹ Eko.

Lasiko ti ikọ tẹlifiṣan Alaroye n lọ kaakiri lati wo bi eto idibo naa ṣe lọ si, la ri awakọ ọhun to fori sọ kọnkere ti wọn fi paala si iyana awọn ọkọ to ba fẹẹ ya lati marosẹ Eko s’Ibadan si ọna CMD Road.

Alaye ti ọkan ninu awọn ẹṣọ alaabo oju popo to tete debi iṣẹlẹ naa ṣe ni pe awakọ yii ti muti yoo, ere buruku lo si n sa bọ lati ibi to ti n bọ, boya nitori bo ṣe mọ pe oun ti rufin eto idibo, tori ijọba ti kede konile-gbele lasiko idibo, pe ko gbọdọ si lilọ-bibọ ọkọ yatọ si awọn ọkọ ti iṣẹ wọn jẹ mọ ti eto aabo tabi idibo.

Nitori bi ọkunrin yii ko ṣe fẹ kawọn agbofinro mu oun, eyi ni wọn lo mu ko ki ere asapajude mọlẹ, agaga nigba to kan awọn ọlọpaa ti wọn duro sirona ni ibudokọ 7Up, amọ bo ṣe ku bii ojo kọja wọn, lojiji lo tun kan awọn ọlọpaa mi-in niwaju, ti wọn ti ko taya dina marosẹ, eyi lo si mu ko ya bara lojiji, ṣugbọn ti ko ri kinni ọhun ṣe daadaa, to si lọọ fori ọkọ Toyota alawọ pupa rẹsurẹsu ti nọmba rẹ jẹ AGL-830CR naa sọ kọnkere ẹgbẹ titi, o hu kọnkeke ọhun tan.

Bo tilẹ jẹ dẹrẹba naa ko fi bẹẹ fara pa, gbogbo iwaju ọkọ ayọkẹlẹ naa lo run jege, taya iwaju ti wọ sẹgbẹẹ, awọn opo to gbe taya duro ti wọn n pe ni ṣafiti (shaft) mejeeji ti yọ bọọlẹ, titi kan ẹnjinni ọkọ naa lewu ti wu.

Ṣa, awọn agbofinro tọkunrin yii n sa fun ni wọn papa waa mu un nibẹ, Ọlọrun si ba a ṣe e, iwaju ẹka ọọfisi awọn Road Safety to wa ni 7Up nijamba naa ti ṣẹlẹ, loju-ẹsẹ ni wọn ti fi ọkọ ti wọn fi n wọ oku mọto wọ awoku ọkọ rẹ lọ sakata wọn, wọn si fi pampẹ ofin mu awakọ ọhun, ibẹ ni yoo ti maa dahun awọn ibeere ti wọn fẹẹ bi i, ki wọn too ka ẹṣẹ rẹ si i leti.

Leave a Reply