Nitori ọmọ rẹ to ku sọsibitu wọn, baale ile kan lu nọọsi daku l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Titi di asiko yii lawọn ọlọpaa ṣi n wa ọkunrin awakọ kan ti wọn lo lu awọn oṣiṣẹ ọsibitu ijọba to wa l’Akurẹ nilu baara latari iku ọmọ rẹ.

Iṣẹlẹ ọhun waye laarin aago mọkanla aarọ si mẹta ọsan ọjọ Abamẹta, Satide ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, nileewosan iya ati ọmọ, to wa lagbegbe Oke-Aro, niluu Akurẹ.

ALAROYE gbọ lati ẹnu ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ile-iwosan naa pe dereba ọhun ati iyawo rẹ ni wọn fi ọkọ ayọkẹlẹ kan gbe ọmọ wọn ọkunrin ti ko ti i ju bii ọmọ ọdun marun-un lọ wa si ọsibitu naa jannajanna pẹlu igbe ‘ẹ dakun ẹ ran wa lọwọ’ ti wọn fi bọnu.

O ni ohun ti oun ṣakiyesi ni pe ẹ̀mí ti fẹẹ bọ lara ọmọ naa ki wọn too gbe e wa sileewosan ọhun lọjọ naa.

Bi wọn ṣe n gbe ọmọ naa de lo ni awọn nọọsi to wa lẹnu iṣẹ sare gba a lọwọ wọn, ti wọn si gbe ẹrọ ti alaisan fi n mi, ọsijin, si i nimu pẹlu itọju oju-ẹsẹ mi-in ti wọn fun un lai beere kọbọ lọwọ wọn.

Lẹyìn eyi lo ni wọn sọ fun awọn obi ọmọ naa ki wọn lọọ san ẹgbẹrun mẹjọ Naira, eyi lo ni wọn n yanju lọwọ ti ọmọdekunrin ọhun fi jade laye.

O ni iwadii awọn fidi rẹ mulẹ pe o ti to bii oṣu mẹfa ti ọmọ yii ti n ṣaisan, ṣugbọn ti wọn de e mọle, ti wọn n lo oogun ibilẹ fun un. Nigba tọrọ fẹẹ yiwọ ni wọn ṣẹṣẹ wa n gbe e bọ nile-iwosan fun itọju.

Bi ọmọ naa ṣe ku lo ni baba rẹ binu wọ inu mọto rẹ, nibi to ti fa ada kekere kan yọ, eyi to kọkọ fi na nọọsi kan titi to fi daku.

Kiakia lawọn oṣiṣẹ yooku ti ba ẹsẹ wọn sọrọ, ti onikaluku si n sa asala fun ẹmi rẹ, ẹni-ori-yọ-o-dile ni wọn fi ọrọ naa ṣe.

O ni loootọ ni wọn sare kan sawọn ọlọpaa B Difiṣan ti ko fi bẹẹ jinna si ọsibitu naa, ṣugbọn ko sohun tawọn agbofinro ọhun le ṣe ni gbogbo asiko ti ọkunrin alajangbila naa fi n dalẹ ru, loju wọn bayii lo ṣe gbe oku ọmọ rẹ sinu ọkọ to gbe wa, o fa iyawo rẹ wọnu mọto, o si ṣina si mọto lẹyin to tẹ ifẹ inu rẹ tan.

Nọọsi mi-in to tun ba wa sọrọ labẹ aṣọ ni ṣe ni ikun ati nnkan ọmọkunrin ọmọdekunrin naa wu gelete nigba ti wọn gbe e de ọdọ awọn. O ni ọpọlọpọ idọti dudu ti awọn fa jade lati imu rẹ fihan pe awọn nnkan ibilẹ ni wọn n lo fun un tẹlẹ.

A gbọ pe awọn oṣiṣẹ ile-iwosan ọhun kọ lati ṣiṣẹ fun ọpọ wakati lẹyin iṣẹlẹ naa, nitori ibẹru.

 

Leave a Reply