Adewale Adeoye
Pẹlu ohun to n ṣẹlẹ nipinlẹ Adamawa ati Kebbi, nipa bi ajọ eleto idibo (INEC), ṣe ti so pe ki wọn dawọ kika esi ibo awọn ipinlẹ mejeeji ọhun duro, ẹgbẹ oṣelu PDP ti sọ pe ohun to daju ṣaka ni pe awọn ọmọ ẹgbẹ awọn lawọn ipinlẹ mejeeji ọhun ni yoo jawe olubori lopin ohun gbogbo.
Alukoro fẹgbẹ oṣelu PDP, Ọgbẹni Debọ Ologunagba, lo sọrọ ọhun nibi to ti n ba awọn eeyan sọrọ. O sọ pe o da ẹgbẹ PDP loju daadaa pe awọn ọmọ ẹgbẹ awọn ni yoo jawe olubori lawọn ipinlẹ bii: Adamawa, Kebbi, Ogun, atawọn ipinlẹ gbogbo ti wọn ti n pẹjọ kotẹmilọrun lori esi idibo ti ajọ INEC gbe sita laipẹ yii.
Bakan naa ni ẹgbẹ PDP tun ki awọn gomina ẹgbẹ naa gbogbo ti wọn gba ipo wọn pada lẹyin esi idibo to waye laipẹ yii. Awọn bii Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Ṣeyi Makinde, pẹlu Gomina ipinlẹ Bauchi, Ọgbẹni Bala Mohammad.
Ologunagba ni lara apẹẹrẹ pe ẹgbẹ PDP jẹ ẹgbẹ to jẹ itẹwọgba daadaa lọdọ awọn araalu lo fa a tawọn gomina ọhun ṣe tun lanfaani lati wọle sipo wọn bayii, ati pe awọn gomina ọhun paapaa ṣiṣẹ daadaa ni saa akọkọ ti wọn wọle lo mu kawọn araalu tun dibo fun wọn lẹẹkan si i.
Ọgbẹni Ologunagba to n gbẹnu ẹgbẹ sọrọ sọ pe igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ naa tun ki awọn gomina kọọkan to jẹ pe wọn ṣẹṣẹ wọle bayii, awọn bii, gomina ipinlẹ Delta, gomina ipinlẹ Akwa-Ibom, gomina ipinlẹ Plateau, gomina ipinlẹ Rivers, ipinlẹ Zamfara, Enugu ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ologunagba ni, “Ki i ṣe ọrọ asọdun rara pe ẹgbẹ PDP jẹ ẹgbẹ pataki kan to jẹ itẹwọgba lọwọ awọn araalu, idi si niyi to fi rọrun daadaa fawọn ọmọ ẹgbẹ naa lati ṣe daadaa ninu ibo gomina to waye laipẹ yii.
“Ohun to daju daadaa ni pe gomina ipinlẹ Adamawa, Alhaji Fintiri ni yoo bori lopin ohun gbogbo, ko si ohun to le ṣẹlẹ, niwọn igba to jẹ pe oun paapaa lo n bori lọwọ ko too di pe wọn da eto ibo kika naa ru, ẹgbẹ PDP ni yoo wọle nipinlẹ Adamawa. Bakan naa lo tun jẹ pe ẹgbẹ wa ni yoo bori nipinlẹ Kebbi, ọmọ ẹgbẹ ta a fa kalẹ lorukọ daadaa laarin ilu, awọn araalu paapaa nifẹẹ rẹ gidi gan-an. Ko sohun ti wọn maa ṣe, ẹgbẹ wa ni yoo bori lawọn ipinlẹ mejeeji yii.
“O si tun da mi loju pe leyin ti wọn ba maa fi dajọ to wa nile-ẹjọ gbogbo, ọpọ ipinlẹ ni ẹgbẹ PDP maa tun gba pada.
Gbogbo ohun to ba gba pata la maa fun un, lati ri i pe INEC ko ṣeru fun wa, o da wa loju bii ada pe awọn ọmọ ẹgbẹ wa ni yoo bori lawọn ipinlẹ ta a darukọ wọn yẹn”