Ọlawale Ajao, Ibadan
Idarudapọ ṣẹlẹ nileewe girama ijọba ipinlẹ Ọyọ kan lọsẹ yii pẹlu bi awọn Fulani darandaran ṣe ya wọ ileewe naa pẹlu ogunlọgọ maaluu wọn, ti wọn si ṣe wọn leṣe rẹkẹrẹkẹ.
Ileewe ọhun ti wọn pe ni Alaropo Nla Community Grammar School, to wa nijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Ọyọ, lo gba awọn alejo ọran naa lojiji, lasiko ti awọn akẹkọọ ileewe naa n gbaradi fun idanwo lọwọ, ti ọrọ si di bo o lọ, o yago.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, awọn gende-kunrin Fulani ọhun to ogun (20) niye, gbogbo wọn ni wọn si dihamọra pẹlu oriṣiiriṣii nnkan ija oloro bii ida, ada, ọbẹ pẹlu ọpa ti wọn fi n da maaluu.
Ọpọ olukọ ati akẹkọọ ileewe ọhun ni wọn ṣe leṣe, bẹẹ lawọn mi-in fara gbọgbẹ nibi ti wọn ti n sa asala fun ẹmi wọn.
Olukọ kan to n jẹ Ọgbẹni Paul Ọladele wa lara awọn ti wọn ṣeṣe nibi ikọlu ọhun, niṣe ni wọn ṣa a ladaa bii igba ti awọn ọmọọdẹ ba n ko ada bo odu ọya ninu igbo ọdẹ.
Gẹgẹ bi ọkan ninu awọn olugbe agbegbe ileewe naa ṣe ṣalaye, “Emi naa n lọ sinu sukuu yẹn ni, o jẹ lasiko ti awọn akẹkọọ ṣẹṣẹ kuro lori ila ni, wọn n mura lati bẹrẹ iṣẹ akọkọ laaarọ ọjọ naa, ṣadeede lawọn Fulani darandaran wọnyi da awọn maaluu wọn wọbẹ, ti awọn maaluu yẹn si bẹrẹ si i fi awọn nnkan ọgbin wọn jẹ.
“Gbogbo ariwo ti awọn olukọ atawọn ọmọọleewe yẹn n pa pe ki wọn yee fi maaluu jẹ oko awọn mọ ko wọ awọn Fulani wọnyẹn leti, kaka bẹẹ, niṣe ni wọn doju ija kọ wọn”.
Abilekọ Grace Alamu to jẹ ọkan ninu awọn ọga agba ileewe naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni awọn ti fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti, wọn si ti bẹrẹ iwadii lori ẹ nitori wọn ti waa ṣabẹwo sileewe ọhun lati bẹrẹ awọn iwadii ti wọn fẹẹ ṣe.