Adewale Adeoye
Ẹgbẹ to n ja fun awọn ẹya ilẹ Yoruba, Afẹnifẹre, ti sọkọ ọrọ si Minisita eto iroyin ati aṣa nilẹ yii, Alhaji Lai Mohammed, lori bo ṣe sọ pe eto idibo to waye lorilẹ-ede yii lọdun yii, lo daa ju lọ latigba ti a ti gba ominira lọwọ awọn oyinbo.
Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi sita niluu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, eyi ti Akọwe agba ẹgbẹ naa, Oloye Ṣọla Ebieni, fọwọ, si to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti bu ẹnu atẹ lu minisita ọhun lori bo ṣe gbe oṣuba nla fun bi eto idibo yii ṣe lọ.
Ebieni ni ko soootọ kankan ninu ohun ti Lai Mohammed sọ nipa eto idibo ọhun rara, o ni eru pọ gidi gan-an ninu idibo naa ju ohun ti minisita yii n sọ lọ.
Ọkunrin naa sọ pe, ‘Iyalẹnu nla gbaa lo jẹ pe pẹlu pe bi ilẹ Naijiria ṣe jẹ ọkan pataki lara awọn ilẹ Adulawọ to gbayi ju lọ lagbaaye, awọn kọọkan ṣi tun wa ninu ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ti wọn n fi dudu pe funfun fun wọn. Iru awọn eeyan naa ni wọn n lọ soke okun lati maa lọọ parọ ohun ti ko ṣẹlẹ nilẹ wa fun wọn, to si jẹ pe ko soootọ kankan ninu ohun ti wọn n sọ faraye gbọ.
‘‘Lara iru awọn eeyan yii ni Minisita eto iroyin ilẹ wa, Alhaji Lai Mohammed, to lọọ parọ banta banta fawọn oniroyin oke okun, nibi to ti sọ pe gbogbo nnkan lo lọ deede nilẹ wa lakooko ibo gbogbogboo to waye laipẹ yii.
‘‘Pẹlu pe alaga ajọ eleto idibo ( INEC), paapaa sọ nita gbangba pe eto idibo ọhun ku die kaato, Lai Mohammed tun lọọ parọ nla loke okun pe gbogbo nnkan lo lọ deede lakooko ibo ọhun. Kẹ ẹ si maa wo o o, ọpọ lara awọn ti Lai lọọ ba loke okun naa lawọn paapaa mọ ohun to ṣẹlẹ lasiko ibo ọhun’’.
Ebiseni ni ko soootọ kankan ninu ọrọ ti Alhaji Lai Mohammed sọ pe INEC nikan lo le sọ bi yoo ṣe kede akojọpọ esi ibo ilẹ wa, pe bi o ba wu wọn, wọn le ṣe e ni eyi ti wọn n fọwọ kọ silẹ, O ni niṣe lo yẹ ki INEC tẹle gbogbo ohun to wa ninu ilana iwe ofin ilẹ wa nipa eto idibo ti wọn ṣe.
Akọwe Afẹnifẹre yii tun ta ko ọrọ ti minisita naa sọ pe Aarẹ Mohammed Buhari ko faaye gba pe kẹnikẹni lo ọlọpaa ilẹ wa lati fi ṣeru lakooko ibo ọhun. O ni ki i ṣe pe awọn oloṣelu ilẹ wa lo awọn ọlọpaa lati fi ṣeru ibo nikan, ṣugbọn ṣe ni wọn tun gbe oju sẹgbẹẹ kan lakooko tawọn ọmọọta tawọn oloṣelu kọọkan n lo n dunkooko mọ awọn alatako wọn, bakan naa ni awọn ọmọọta kan lu awọn ọmọ ẹgbẹ alatako, tawọn agbofinro ko si ri ohunkohun ṣe si i.
O fi kun un pe pe awọn oloṣelu kọọkan padanu ipinlẹ wọn sọwọ ẹgbẹ alatako ki i ṣe tuntun rara, nitori pe awọn to lọọ dibo lawọn ipinlẹ naa ko gba gbẹrẹ rara lo ṣee ri bẹẹ.
Tẹ o ba gbagbe, Lai Muhammed lọ sorileede Amẹrika laipẹ yii, nibi to ti ba awọn oniroyin sọrọ, to si ṣapejuwe eto idibo to waye labẹ iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari gẹgẹ bii eyi to daa ju lọ lorilẹ-ede yii.