Ismail Adeẹyọ ati Faith Adebọla
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni ọlọpaa kan pade iku ojiji nibi ija to waye laarin awọn ọlọkada atawọn ọlọpaa nipinlẹ Eko, bẹẹ lọpọ eeyan si dero ọsibitu nibi ti wọn ti n gba itọju pajawiri lọwọ latari bi wọn ṣe fara gbọgbẹ yanna-yanna.
Iṣẹlẹ yii waye lakooko ti ọlọpaa to doloogbe ọhun fẹẹ fi pampẹ ofin mu ọlọkada kan to n gbe ero gba agbegbe Sẹlẹ-Ijesha, lọna Mile 2 si Apapa.
Ẹ oo ranti pe agbegbe yii wa lara awọn ibi tijọba ipinlẹ Eko ti ka fifi ọkada gbero leewọ, ofin ọhun si mulẹ lati ọpọ oṣu diẹ sẹyin, ṣugbọn bi eto idibo sipo gomina, eyi to waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, to lọ yii, ṣe n ku dẹdẹ, ijọba Babajide Sanwo-Olu dẹwọ ofin naa, wọn si tun fawọn ọlọkada laaye lati maa ṣọrọ-aje wọn bii ti tẹlẹ.
Alaroye gbọ pe bi ọlọpaa ti wọn o darukọ rẹ yii ṣe bu ọkada tọkunrin naa gun so, to si fẹẹ gba a lọwọ rẹ, oun ati ọlọkada bẹrẹ si i lọ maṣinni ọhun mọ ara wọn lọwọ, eyi lo si mu kawọn ọlọkada ẹlẹgbẹ rẹ ṣafiyesi ohun to ṣẹlẹ, koloju too ṣẹ ẹ, awọn ọlọkada ti ya bo ọlọpaa naa, bo tilẹ jẹ pe awọn agbofinro mi-in wa nibẹ pẹlu lati gbeja ọkan lara wọn, ija bẹrẹ latari bawọn ọlọkada yii ko ṣe gba ki wọn fi pampẹ ofin gbe maṣinni ti wọn lo rufin irinna naa lọ.
Lasiko laasigbo ọhun, awọn ọlọkada kan fara ṣeṣe, eyi lo si mu kawọn naa fibinu lu ọkan lara awọn ọlọpaa naa pa loju-ẹsẹ.
Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ pe ọlọpaa ti wọn pa nifọnna-ifọnṣu yii kọ lo mu ọkada naa, wọn ni niṣe loun kan yinbọn soke lati ṣẹru ba awọn ti n ṣe fa-n-fa naa, amọ, oju ina kọ lewura n hu irun, awọn alariwo ti wọn ti fọna soju naa ya bo o, wọn si pa a bii ejo aijẹ.
Ẹlomi-in tọrọ naa tun ṣoju ẹ, Ọgbẹni Dẹhinde, ṣalaye fawọn oniroyin pe awọn ọlọpaa ti kọkọ kuro lagbegbe iṣẹlẹ naa nigba ti wọn ri i pe wọn ti pa ọkan lara wọn, lẹyin eyi ni ọn ṣigun pada wa sibi iṣẹlẹ naa.
Kete tawọn ọlọkada naa ri ọgọọrọ ọlọpaa yii ni wọn sa lọ.’’
O tẹsiwaju pe oriṣiiriṣii ohun ija oloro lo wa lọwọ awọn ọlọkada naa, bii ibọn, ada, ọbẹ, aake atawọn nnkan mi-in.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S. P Benjamin Hundeyin, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE lo ti ni yatọ si ọlọpaa inspẹkitọ ti wọn gbẹmi ẹ yii, wọn tun ṣe DPO kan leṣe gidigidi.
O ni ọwọ awọn ti tẹ afurasi meji lori iṣẹlẹ yii, ọkada tawọn si ti mu ti di mọkanlelogoji.
O fi kun pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ naa.