Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ankoo, bii aṣọ oniṣuga, ni tọkọ-tiyawo kan, Bello Owolabi ati iyawo rẹ, Jumokẹ, fi ọrọ ẹgbẹ okunkun ṣe. Bi ọkọ ṣe wa ninu ẹgbẹ naa, bẹẹ niyawo paapaa jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun, ṣugbọn ọwọ awọn agbofinro ti ba wọn, yẹkinni kan ko si le yẹ ẹ, awọn mejeeji yoo jọ marede lọ siwaju adajọ ni, nigba tawọn ọlọpaa ba gbe wọn de kootu lati ṣalaye ohun to sun wọn dedii ẹgbẹ ti ko bofin mu ọhun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe awọn tọkọ-tiyawo yii lo ṣe agbatẹru akọlu ati ipaniyan to waye lera-lera laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji nipinle Ekiti laipẹ yii, eyi to fa iku mẹta ninu wọn laarin ọjọ mẹta sira wọn ni Ado-Ekiti.
Wọn sọ eleyii di mimọ lasiko ti wọn n ṣafihan awon afurasi ọdaran meji naa atawọn afunrasi ajinigbe, ole ati awọn afipa ba ni lo pọ mẹẹẹdogun miiran niluu Ado-Ekiti, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣalaye pe ọkọ iyawo yii, Bello Owolabi, jẹ gbajumọ pataki laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, o si jẹ oloye laarin wọn.
Ọkunrin ti wọn n pe ni Awolu, laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun ni wọn lo lu iyawo rẹ lasiko ti ede aiyede bẹ silẹ laarin wọn, to si da apa si gbogbo ara obinrin yii.
Eyi ni ALAROYE gbọ pe o bi ẹgbọn ọmọbinrin yii toun naa jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun ninu ẹgbẹ miiran ninu, lo ba ko awọn ọmọ ẹgbẹ tiẹ naa jọ, lo ba lọọ ka ọkọ aburo rẹ yii mọle, eyi to pada da wahala nla silẹ laarin awọn ẹgbẹ okunkun mejeeji.
Abutu fi kun un pe awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun ko ni i pẹẹ foju bale-ẹjọ