Monisọla Saka
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni ile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Ogudu, nipinlẹ Eko, sọ tọkọ-taya kan, Ọmọlara Alashe, ẹni ọdun mẹrindinlogoji (36), ati ọkọ ẹ, Ramọni Lateef, ẹni ogoji ọdun (40), sẹwọn, nitori bi wọn ṣe n fiya jẹ ọmọ ọdọ wọn, ti wọn si tun n fipa ba pa obinrin ẹni ọdun mọkandinlogun (19) naa lajọṣepọ.
Awọn tọkọ-tiyawo naa ti wọn n gbe laduugbo Igbonla, Ketu, nipinlẹ Eko, ni wọn n kawọ pọnyin niwaju Onidaajọ Tanimọla, fun ẹsun ifipabanilopọ, iloni nilokulo, ati ole jija.
Bo tilẹ jẹ pe awọn afurasi mejeeji yii rawọ ẹbẹ sile-ẹjọ pe ki adajọ ṣiju aanu wo awọn, Arabinrin M. O. Tanimọla, ko gba ipẹ wọn.
Gẹgẹ bi Agbefọba, Insipẹkitọ Donjor Perezi, to wọ awọn ọdaran olujẹjọ mejeeji lọ si kootu ṣe wi, o ni ninu oṣu Kẹta, ọdun yii, lawọn afurasi ọhun ṣe aṣemaṣe yii ninu ile wọn.
O ni eyi ọkọ to jẹ olujẹjọ kin-in-ni, lo fipa ba ọmọọdọ wọn, ẹni ọdun mọkandinlogun, lo pọ, ti iyawo to jẹ olujẹjọ keji, maa n saaba ji ọmọbinrin naa laaarin oru, lẹyin to ba ja a sihooho goloto tan ni yoo sọ fọkọ ẹ pe ko ba a laṣepọ, lai ṣe pe o tinu ọmọ naa wa.
O tẹsiwaju pe nigba akọkọ, Alashe lu ọmọ naa gidigidi, lẹyin naa lo ti ika ọwọ ẹ bọ oju ara ọmọọdọ yii titi ti ẹjẹ fi n jade lara ẹ. Bakan naa ni wọn tun lo n gbẹsẹ le owo oṣu ẹ, o tun gba kaadi ATM banki GTB rẹ, ati siimu kaadi rẹ.
O ni lẹyin ti wọn fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti ni wọn lọọ fi panpẹ ofin gbe e.
Perezi tẹsiwaju pe iwa ti awọn afurasi ọdaran naa hu ta ko ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko, ti ọdun 2015. Ati pe apa kan abala iwe ofin naa fidi ẹ mulẹ pe ẹwọn ọdun mẹta ni ki wọn ju ẹni to ba jale si.
Adajọ Tanimọla waa paṣẹ pe ki wọn lọọ fi awọn mejeeji pamọ sọgba ẹwọn to wa niluu Ikoyi, nipinlẹ Eko, titi toun yoo fi gba imọran lati ileeṣẹ ijọba to n ri si eto igbẹjọ, Director of Public Prosecution, DPP.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun ta a wa yii.