Lẹyin idajọ ile-ẹjọ to ga ju lọ: Ijo, ilu at’orin lawọn oṣiṣẹ fi ki Adeleke kaabọ s’ọfiisi l’Ọṣun 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Tilu-tifọn lawọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọṣun fi ki Gomina Ademọla Adeleke kaabọ si sẹkiteriati ijọba to wa ni Abere, niluu Oṣogbo, laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un, ọdun yii.

Eleyii ko ṣẹyin bi ile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede yii ṣe sọ niluu Abuja lọjọ Tusidee, ọjọ kẹsan-an,  oṣu yii pe Adeleke lo jawe olubori ninu idibo gomina to waye loṣu Keje, ọdun 2022.

Lati nnkan bii aago meje aarọ ọjọ Wẹsidee lawọn oṣiṣẹ ijọba naa ti n jo, ti wọn si n kọrin, pe imọlẹ ti pada bori okunkun nipinlẹ Ọṣun.

Koda, awọn kan ninu wọn gbe gaasi ati awọn nnkan idana lọ sibẹ, ti wọn si n din akara funraa wọn jẹ.

Bi mọto gomina ṣe yọ lọọọkan ni wọn fọn si oju titi, ti wọn si n fi ijo ki i kaabọ si ọfiisi, ti oun naa si n juwọ si wọn pẹlu ẹrin lori ọkọ to jokoo si.

Bayii ni gbogbo wọn jọ kọwọọrin lọ si ọfiisi gomina.

Tẹ o ba gbagbe, lati ọdun to kọja ti ajọ eleto idibo ti kede Adeleke gẹgẹ bii gomina Ọṣun ni ẹgbẹ APC ti ni ọrọ naa ko le ri bẹẹ, ti wọn si gba kootu lọ.

Bo tilẹ jẹ pe igbimọ Tiribuna to kọkọ gbọ ẹjọ naa da Gboyega Oyetọla lare, sibẹ, idalare yii ko tọjọ pẹlu bi ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ṣe da a pe ẹjọ naa ko lẹsẹ nilẹ, to si ni ki Gomina Ademọla Adeleke maa ṣejọba rẹ lọ.

Ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa lo fọba le e pẹlu bi wọn ṣe fọwọ osi da ẹjọ ti gomina Ọṣun tẹlẹ, Gboyega Oyetọla ati ẹgbẹ APC pe nu. Wọn ni ko lẹsẹ nilẹ.

Leave a Reply