Buhari be awọn asofin, ẹ jọwọ, ẹ fọwọ sí ẹgbẹrin milionu dola ti mo fẹẹ ya

Monisọla Saka

L’Ọjọruu Wẹsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari, kọwe sawọn aṣofin lati buwọ lu ẹyawo ẹgbẹrin miliọnu dọla, ($800 million), toun fẹẹ ya.

Ninu lẹta ti Buhari fi ṣọwọ sileegbimọ aṣofin agba, ti Sẹnetọ Ahmed Lawan, ti i ṣe olori ile naa ka si gbogbo awọn aṣofin ẹgbẹ ẹ leti ni Buhari ti sọ pe nitori igbaye-gbadun awọn araalu loun ṣe fẹẹ ya owo ọhun. O ni eyi wa ninu eto ti ijọba apapọ gbe kalẹ fawọn mẹkunnu orilẹ-ede yii lati ṣe iranwọ fun wọn.
O tẹsiwaju pe eto oju aanu, ti ko ni ojuṣaaju ninu, tijọba apapọ gbe kalẹ ni, ati pe banki agbaye lawọn yoo ti ya owo naa, ọdọ awọn alaini jake-jado orilẹ-ede yii lawọn yoo si pin owo naa si.

O fi kun un pe awọn igbimọ ijọba apapọ, Federal Executive Council, (FEC), ti fọwọ si i pe koun ya a, ati pe aṣẹ nikan lo ku toun n reti latọdọ awọn aṣofin koun too gbe igbesẹ naa.
Buhari ni ti wọn ba le buwọ lu aba eto ẹyawo yii, inu asunwọn banki ẹni kọọkan tawọn ba yan lati fun lowo, lawọn yoo fi ranṣẹ si.

Ṣaaju akoko yii, ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2023 ta a wa yii, ni Minisita feto inawo ati eto ilu, Zainab Ahmed, ti kede pe ijọba apapọ yoo ya miliọnu lọna ẹgbẹrin dọla, ti wọn yoo si pin in fun idile bii aadọta miliọnu awọn ọmọ Naijiria ti wọn ko ri ja jẹ, tabi ki wọn pin in fun idile bii miliọnu mẹwaa, gẹgẹ bii owo iranwọ ori epo ti wọn fẹẹ fi ṣanfaani fawọn araalu.
Zainab ni awọn fẹẹ pin owo yii, ni imurasilẹ fun owo iranwọ ori epo rọbi ti wọn fẹẹ yọ latinu oṣu Kẹfa, ọdun yii.

Ileeṣẹ to n ri si ọrọ gbese ti ilẹ Naijiria jẹ, The Debt Management Office (DMO), kede laipẹ yii pe ibi ti gbese ti ilẹ Naijiria jẹ de duro nigba ti wọn wo o ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila, ọdun to kọja, ti fo fẹrẹ lọ si tiriliọnu mẹrindinlaaadọta, tabi biliọnu mẹtalelọgọrun-un owo Dọla.

Lasiko ti ileeṣẹ DMO, n ṣe itupalẹ bi ọrọ gbese ṣe jẹ, wọn ṣalaye pe odidi tiriliọnu meje Naira lo gun ori gbese ti Naijiria jẹ silẹ si iye to wa lọdun 2021.

Niwọnba ọjọ perete to kú ti Buhari yoo lo nipo Aarẹ bayii, pẹlu bi yoo ṣe gbe ipo iṣakoso orilẹ-ede yii silẹ fun aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ko sẹni to le sọ iye ti gbese Naijiria yoo jẹ titi igba naa, bẹẹ lawọn aṣofin ko ti i sọ boya wọn yoo fọwọ si ẹyawo ọhun tabi wọn ko ní í fọwọ sí i.

Leave a Reply