Ijọba ti ni awọn yoo fofin de awọn ọti ti wọn n ṣe keekeeke, eyi ti wọn n ṣe sinu ọra ti wọn n pe ni pẹlẹbẹ, eyi ti wọn n ṣe sinu igo atawọn lailọọnu mi-in. Ọga agba ajọ to n ri si ọrọ ounjẹ ati oogun lilo nilẹ wa, (NAFDAC), Ọjọgbọn Mojisọla Adeyẹye, lo sọrọ naa ni Satide opin ọsẹ to kọja.
Obinrin naa ni, ‘‘Ileeṣẹ NAFDAC, labẹ idari ileeṣẹ eto ilera ilẹ wa fi n to gbogbo ilu leti pe opin yoo de ba pipese awọn ọti lile sinu ọra, ike ati igo keekeeke.’’
Obinrin naa ni mimu awọn nnkan wọnyi lai bikita n ṣe akoba fun awọn to n mu un lai kiyesara, bẹẹ lo tun n ṣakoba fun ilera ati aabo awọn araalu.
Adeyẹye ni bi awọn eeyan ṣe n ni anfaani si awọn ọti pẹlẹbẹ ateyi ti wọn n ṣe sinu igo to jẹ olowo pọọku yii n jẹ ki awọn eeyan ṣi i lo nipa mimu un ni amuju, eyi to ni o n fa aṣilo ọti, to si n ṣakoba ti ko kere fun awujọ wa.
O fi kun un pe iwadii Ajọ Eleto Ilera Agbaye (WHO) jẹ ko di mimọ pe mimu awọn ọti yii lai bikita ti ṣokunfa iku eeyan to to bii miliọnu mẹta kaakiri agbaye, ọpọ ni ilera wọn ko da pe mọ, to si ti sọ ọkẹ aimọye eeyan di alaabọ ara.
Adeyẹye ni ojuṣe NAFDAC ni lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn alẹnulọrọ lawujọ, lati din ọsẹ ti awọn ilokulo ọti yii n ṣe ku.
Se OTOGE , O TOPE , O JASOPE ni abi OYIWO . Gbogbo oro aje loti denu kole , inkan won gogo , eto EKO o lo dede mon , kosi IWOSAN tope ye . Eto ABO ti da enu kole . Dipo INAN MANANMANAN , INAN MANNAN MANNAN ni won fun wa . Oto ni oun ti a ni ki OKOBO won o boo , sugbon IGBA ABERE ni o ni oun le bo monjumon . Ejo ti nbe lodo Eledua ti koja ejo onisiga . Ayafi ki Eledua gbawa lowo awon JEGUDU JERA OLOSELU . Sugbon o , eje ki a ranti wipe Olorun koni so kale , AWA ni a fe gba ara wa sile lowo won ni igba kigba ti a ba setan .
Odara, nitori wipe oti yii n se akoba fun kidinrin a won to n muan. Opolo awon tonmu ni o n kopa ninu iwa ifipabanilopo.