Adewale Adeoye
Nigba to ku ọjọ diẹ ko kuro nipo gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Kaduna, Malam Nasir El-Rufai ti paṣẹ pe ki wọn gba ade, ọpa-aṣẹ, irukẹrẹ ati gbogbo ohun to ni i ṣe pẹlu nnkan ti wọn fi le da awọn ọba alaye meji kan, Ọba Jonathan Paragua Zamuna ati Ọba Aliyu Illah Yamman, ti wọn n ṣakooso lori agbegbe Pirigi ati Arak, nipinlẹ naa mọ lọwọ wọn ni kia.o
Lori ẹrọ ayelujara to jẹ ti Gomina Nasir El-Rufai lo ti kọkọ kede yiyọ awọn ọba mejeeji ọhun nipo fawọn araalu, ko too di pe Hajiya Umma Ahmed to jẹ Kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati fifi eeyan joye niluu naa tun fidi rẹ mulẹ, to si sọ pe yiyọ awọn ọba alaye mejeeji naa bẹrẹ lati lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.
El-Rufai kọ ọ sori ẹrọ ayelujara rẹ pe ‘Ijọba ipinlẹ Kaduna n fi akoko yii sọ fawọn araalu gbogbo pe Gomina Nasir El-Rufai ti bu ọwọ lu yiyọ awọn ọba alaye mejeeji yii, Ọba Jonathan Paragua Zamuna ati Ọba Aliyu Illah Yamman, ti wọn n ṣakoso lori agbegbe Pirigi ati Arak, nipinlẹ Kaduna, bẹrẹ lati ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii”.
Kọmiṣanna ọhun ni igbesẹ tijọba ipinlẹ naa gbe wa ni ibamu pẹlu ofin to gbe jijẹ oye ọba kalẹ nipinlẹ naa. Ti wọn si ti yan olori agbegbe Garun Karunma, Ọgbẹni Babangida Sule, ko maa dari agbegbe Piriga, titi digba ti wọn yoo fi yan olori tuntun sipo naa. Nigba ti Ọgbẹni Gomna Ahmadu to jẹ akọwe agba ilu Arak, yoo maa dari ilu Arak titi digba tijọba yoo fi yan ẹlomiran.
Ẹsun ti won fi kan wọn ni pe Ọba Illyah Yammah fi awọn oloye mẹrin kan jẹ lai jẹ pe o tẹle awọn ilana to yẹ lori ọrọ oye awọn eeyan naa. Ati pe, ki i gbe inu ilu to n ṣakoso lori rẹ rara.
Ni ti Ọba Jonathan Zamuna, ẹṣẹ toun ṣẹni pe ko mojuto akooso ilu naa rara debii pe ija igboro kan bẹ silẹ níbẹ, to si mu ọpọ ẹmi awọn araalu naa.
Wọn fi kun un pe ọba alaye naa ki i gbe inu ilu to ti jẹ ọba naa rara eyi tawọn alaṣẹ ijoba ipinlẹ naa sọ pe ki i ṣohun to daa rara.
Bẹẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni Gomina Nasir El-Rufai sọ pe ijọba oun ko ni i ye le awọn ọbayejẹ kọọkan ti wọn wa lẹnu iṣẹ ijọba ipinlẹ naa danu, ati pe titi di ọjọ toun yoo lo gbẹyin ninu isakoso oun loun yoo fi maa wo awọn ile kọọkan ti wọn ko wa ni ibamu ati ilana ikọle ipinlẹ naa danu bayii.