Monisọla Saka
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni ile-ẹjọ giga kan niluu Abuja, binu da ẹjọ tawọn kan pe ta ko eto iburawọle Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima, gẹgẹ bi aarẹ ati igbakeji rẹ nu.Awọn eeyan mẹta ti wọn pe ara wọn ni ọmọ ilẹ Naijiria tọrọ ka lara (Concerned Citizens), Praise Isaiah, Paul Audu ati Anongu Moses, ni wọn fẹsun kan Tinubu pe o parọ ọjọ ori ninu iwe ibura rẹ lọdọ ajọ INEC, bakan naa ni wọn tun sọ pe irọ lo pa, nigba to loun ki i ṣe ọmọ orilẹ-ede mi-in yatọ si Naijiria, lojuna ati le ribi dupo aarẹ.Wọn ni ko si ootọ kan ninu ohun ti Tinubu kọ nipa ara ẹ sinu iwe naa, nitori yatọ si pe o jẹ ọmọ orilẹ-ede Naijiria, o tun ni iwe idanimọ ọmọ orilẹ-ede Guinea, eyi to mu ko jẹ ọmọ oniluu, lorilẹ-ede meji ọtọọtọ, ti ko si fihan ninu fọọmu rẹ. Wọn tun sọrọ siwaju si i pe nigba ti Tinubu n fi ye gbogbo eeyan pe ọdun 1957 ni wọn bi oun, iwadii ti fihan pe ọdun 1952 ni wọn bi i, ati pe iwa to hu ta ko ofin orilẹ-ede yii.Wọn waa bẹ ile-ẹjọ pe ko da eto iburawọle wọn duro, ati pe ki wọn fofin de Tinubu, lati ma ṣe le dupo kankan, niwọn ọdun mẹwaa sigba ta a wa yii.Lasiko ti Onidaajọ Ọmọtọshọ n gbe idajọ rẹ kalẹ lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, o ni ẹjọ ti wọn pe ta ko aarẹ tuntun naa ko lẹsẹ nilẹ, ati pe ile-ẹjọ ko ni i le gbọ ẹjọ lẹnu wọn, nitori ki i ṣe ẹjọ to dangajia to lati de iwaju adajọ, bẹẹ si ni awọn ko ni i le faaye gba a, nitori bo ṣe ni i ṣe pẹlu eto idibo aarẹ oṣu Keji, ọdun yii. Adajọ tun ni igbesẹ lati fi eto idajọ yi ẹrẹ̀ ni wọn n gbe, nitori naa, oun yi ẹjọ wọn danu.O ni ẹjọ ti wọn pe lati da eto iburawọle fun aarẹ atigbakeji ẹ, to ku bii ọjọ meloo kan yii duro le da omi alaafia orile-ede yii ru, ko si tun dabaru eto iṣejọba awa-ara-wa lorilẹ-ede yii, ati pe oludije dupo nikan lo lẹtọọ lati dide ta ko ọrọ ọjọ ori, iwe-ẹri tabi ohunkohun to ba ni i ṣe pẹlu ọrọ oludije dupo kan ninu eto idibo.O sọrọ siwaju si i pe niwọn igba ti eto idibo ti wa sopin, ile-ẹjọ kotẹmilọrun nikan lo lẹtọọ lati ṣedajọ lori iru ẹjọ to tibi idibo wa ọhun.Ninu idajọ ẹ lo ti ni ko si koko kankan ninu ẹjọ ti wọn pe.O bu ẹnu atẹ lu awọn agbẹjọro awọn olupẹjọ pe ẹjọ to le foju eto idajọ gbolẹ ni wọn n ba awọn onibaara wọn ṣe. O lawọn atawọn olupẹjọ n fi akoko ile-ẹjọ ṣofo ni, ti wọn si tun n tẹ ofin ile-ẹjọ loju mọlẹ.Lẹyin naa lo paṣẹ pe miliọnu mẹẹẹdogun Naira ni wọn yoo san gẹgẹ bii owo itanran fun bi wọn ṣe da ile-ẹjọ laamu. O ni miliọnu mẹwaa yoo jẹ ti Tinubu, miliọnu marun-un fawọn ẹgbẹ oṣelu APC, ti awọn agbẹjọro awọn olupẹjọ mẹtẹẹta yoo si tun san miliọnu kan Naira, lorukọ awọn olupẹjọ, fawọn olujẹjọ mejeeji.