Adewale Adeoye
Ni bayii, awọn ọlọpaa agbegbe Itas Gadau, nijọba ibilẹ Itas Gadau, nipinlẹ Bauchi, ti sọ pe, ọdọ awọn ni Ọgbẹni Ibrahim Abdullahi, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27) kan ti wọn fẹsun ifipa bani lo pọ kan, wa bayii, to si n ran awọn lọwọ ninu iwadii awọn, ati pe gbara tawọn ba ti pari iwadii nipa ẹsun ti wọn fi kan-an tan, lawọn maa foju rẹ bale ẹjọ.
Ẹsun ti wọn fi kan Ibrahim to sọ ọ dero ahamọ ọlọpaa ni pe wọn lo lọọ fipa ba ọmọdebinrin ọmọọdun meje kan lo pọ ninu ile igbọnsẹ kan to wa nileewe ti ọmọ ọhun, ti wọn forukọ bo laṣiiri ti n kọ ẹkọ rẹ lọwọ, eyi to wa nijọba ibilẹ Itas Gadau yii kan naa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ ọhun, SP Ahmed Mohammed Wakili, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lọjọ Tọsidee, ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, sọ pe, niṣe ni Ibrahim da ọgbọn buruku kan, wọn lo tan ọmọdebinrin naa lọ sile igbọnsẹ kan ileewe lọjọ to huwa buruku ọhun, to si fipa ba a laṣepọ ko too fi i silẹ.
Alukoro ọhun ni, Ọgbẹni Umaru Yusuff lo waa fiṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa agbegbe Itas Gadau leti lọjọ kẹtala, oṣu Karun-un, ọdun yii, kawọn ọlọpaa too tara ṣaṣa lọọ fọwọ ofin mu afurasi naa nile rẹ, ko ma ba a sa lọ
Alukoro ọhun ni ‘loju–ẹsẹ tawọn ọlọpaa ti gbọ sọrọ naa ni wọn ti lọ ọ fọwọ ofin mu Ibrahim nile ẹ, DPO teṣan naa paapaa tẹle ikọ awọn ọlọpaa to lọọ ṣabẹwo si ibi ti Ibrahim ti wu iwa radarada naa, ta a si ti gbe ọmọdebinrin naa lọ si ọsibitu ijọba kan to wa lagbegbe Itas Gadau fun itọju, nibẹ naa ni wọn ti fidi rẹ mulẹ lẹyin ayẹwo ti wọn ṣe fọmọ ọhun pe loootọ ni ẹnikan ti fipa ba ọmọ naa sun.
Alukoro ọhun ni ọrọ yii ko ru’ju rara, bawọn ba ti pari gbogbo iwadii awọn tan nipa ẹsun tawọn fi kan Ibrahim lawọn maa ti foju rẹ bale-ẹjọ ko le lọ jiya ohun to ṣe.