Wahala n bọ o, nitori Tinubu, ẹgbẹ oṣo at’ajẹ pẹlu awọn pasitọ fẹẹ kọju ija sira wọn

Monisọla Saka

Afaimọ ki ija nla ma waye laarin awọn ẹgbẹ oṣo ati ajẹ lorileede yii pẹlu awọn pasitọ tawọn naa n mura lati lọ sibi iburawọle fun Aṣiwaju Tinubu ti wọn dibo yan bii aarẹ Naijiria.

Ni ipalẹmọ fun ayẹyẹ iburawọle aarẹ tuntun yii, eyi ti yoo waye lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, Pasitọ Dokita Paul Eneche, ti ijọ Dunamis International Gospel Centre, ti kilọ fawọn ẹgbẹ ajẹ ati oṣo ilẹ Naijiria lati ma ṣe kọja aaye wọn pẹlu Abuja ti wọn lawọn n bọ lọjọ iburawọle fun aarẹ tuntun ọhun.

Ninu atẹjade ti ẹgbẹ awọn oṣo ati ajẹ ọhun fi sita ni agbẹnusọ wọn, Okhue Obo, to sọrọ pe ki Tinubu ma foya, nitori gbogbo awọn ifẹhonu ati iwọde ti wọn n ṣe ta ko o ko le tu irun kankan lara ẹ, ihalẹ lasan ni, wọn ni bii ike lawọn wa lẹyin rẹ. Bakan naa ni wọn ṣeleri lati wa nibi iburawọle rẹ, ki ohun gbogbo le baa lọ bo ṣe yẹ.

Ọrọ ti wọn sọ yii lo mu ki ojiṣẹ Ọlọrun naa koro oju si ọwọ tawọn ẹlẹyẹ naa n gbe. O waa sọ fawọn pasitọ ẹlẹgbẹ rẹ mi-in lati ya awọn aaye kọọkan kaakiri ilu naa si mimọ lati le gbogun ti awọn ogun eṣu (iyẹn awọn oṣo at’ajẹ) ti wọn lawọn fẹẹ fọ ilu mọ.

Lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Pasitọ Eneche sọ pe awọn ẹmi eṣu kan lawọn n bọ waa fọlu mọ, ṣugbọn tawọn Ojiṣẹ Ọlọrun ẹgbẹ oun ko ba ti le kọju ija si awọn ẹni eṣu ti wọn wa lati inu ina apaadi, to jẹ pe ọna lati da aburu silẹ ni erongba wọn, a jẹ pe awọn ko lẹtọọ lati maa waasu ihinrere niyẹn.

O waa dabaa pe kawọn Pasitọ le ribi ṣẹgun awọn ẹmi eṣu yii, ẹni kọọkan awọn ni lati tete gbe igbesẹ laarin wakati mẹrinlelogun. O ni ki wọn gbe igo ororo, ki wọn si maa yi gbogbo agbegbe wọn ka, bi wọn ba ṣe n lọ yii ni ki wọn maa ya ori ilẹ si mimọ pẹlu igo ororo ọwọ wọn. Ati pe gbogbo awọn iranṣẹ eṣu ti wọn ba tẹ ilẹ bẹẹ kọja lati waa ṣiṣẹ ibi ni yoo ku.

“Lẹyin ta a ba ti dana sori ilẹ yii, ọmọ ogun eṣu kankan to ba gori ilẹ naa nitori iwa ibi, ti ko ba ku, a jẹ pe ki i ṣe ọba iye ni ọba ta a n sin”.

O waa kilọ fawọn Oṣo ati Ajẹ, pe awọn ti sọ ododo ọrọ fun wọn pe ọwọ awọn ni iṣakoso eto wa, ati pe awọn ko ṣetan lati yi ọkan awọn pada lori ipinnu tawọn ti ṣe. Wọn ni ki ẹnikẹni to ba nifẹẹ ara ẹ ninu wọn ma ṣe gbe igbesẹ aburu kankan, ko ma baa kan idin ninu iyọ.

Ṣaaju akoko yii lawọn ẹgbẹ ajẹ ati oṣo lorilẹ-ede yii ti sọrọ lọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ọdun yii, pe awọn n bọ waa fọ ilu Abuja ati gbogbo agbegbe rẹ mọ, ki Aarẹ tuntun, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, le ribi ṣiṣẹ ẹ.

Laarin ọsẹ ọhun naa ni diẹ lara awọn ọmọ ẹgbẹ ajẹ yii wọlu Abuja wa lati waa ṣiṣẹ iyasi-mimọ ti wọn lawọn fẹẹ ṣe.

Leave a Reply