Ẹ wo Taiwo, awọn oni POS lo n lu ni jibiti n’Ilọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọwọ ti tẹ ogbologboo ole kan, Akinrotimi Taiwo, to n ja awọn oni POS Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lole latọjọ to pẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, lagbegbe Òkèkere.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii, lọwọ tẹ Taiwo, lasiko to fẹẹ lu oni POS kan ti wọn n pe ni Zakariyau Amidu Oniyọ, ti ṣọọbu rẹ wa ni 32B, Opopona Ọmọdàda, Òkèkere, ni jibiti ẹgbẹrun lọna mẹrindinlọgbọn Naira (#26,000).

Taiwo sọ fun Oniyọ pe ko ba oun fi ẹgbẹrun lọna mẹrindinlogun Naira ṣọwọ si akanti oni POS miiran, iyẹn Ọmọ Mummy, o loun yoo fun un lowo ati owo ti yoo fi fi owo naa ranṣẹ. Lẹyin to fun oni POS lowo tan ni afurasi yii n dibọn bii ẹni to fẹẹ ra ṣaja foonu. Lo ba palẹmọ owo pada kuro lori teburu oni POS. Ni kete ti owo naa poora ni Oniyọ figbe ta, lawọn araadugbo ba nawọ gan ọmọkunrin yii, wọn lu u bii ejo aijẹ, wọn si fa a le ajọ Nigerian Security and Civil Defence Corps (NSDC), lọwọ.

Alukoro ajọ naa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ayẹni Ọlasunkanmi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni afurasi ọdaran yii ti maa n ja awọn oni POS lole kaakiri  ilu Ilọrin ati gbogbo agbegbe rẹ, ọjọ ti pẹ ti wọn si ti n wa a pẹlu fọto rẹ. O ṣeleri pe lẹyin tawọn ba pari gbogbo iwadii awọn lawọn yoo gbe afurasi naa lọ si kootu.

 

Aworan Taiwo to n lu oni POS ni jibiti n’Ilọrin ree

Leave a Reply