Baba agbalagba yii fipa b’ọmọọdun mẹsan-an lo pọ, o l’ọmọ naa ṣẹju soun ni

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa kan lagbegbe Gangaraso, nijọba ibilẹ Jada, nipinlẹ Adamawa, ti sọ pe ọdọ awọn ni Ọgbẹni Danladi Wari, baba ẹni ọdun marundinlaaadọrin (65) kan to fipa ba ọmọ ọdun mẹsan-an lo pọ wa, nibi to ti n ran awọn lọwọ ninu iwadii awọn, ati pe, gbara tawọn ba ti pari gbogbo iwadii nipa ẹsun ifipa-bani-lopọ tawọn fi kan an lawọn yoo foju rẹ bale-ẹjọ.

ALAROYE gbọ pe ṣe lọkunrin yii fipa ba ọmọọdun mẹsan-an kan sun lọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, nile rẹ to wa lagbegbe Gangaraso, nijọba ibilẹ Jada, nipinlẹ Adamawa, tawọn si ti fọwọ ofin mu un.

Eṣẹ ti ọkunrin naa ṣẹ ni wọn sọ pe o lodi sofin, tijiya nla si wa fún iru ẹṣẹ bẹẹ ninu ilu naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa, S.P Suleiman Nguroje, to fidii iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin sọ pe baba naa ti jẹwọ, ṣugbọn ohun to sọ ni pe ọmọ ọhun lo fa a toun fi fipa ba a sun, nitori ṣe lo n fọwọ pa oun lara nigba tawọn jọ wa ninu ile.

O ni ṣe lọmọ naa kọkọ waa tọrọ igba Naira lọwo oun, nigba toun sọ fun un pe oun ki ni to iye owo to beere yẹn lọwọ rara lo ba tun ko awọn aṣọ kan wa pe koun ba oun ran an lọfẹẹ, toun si gba a lọwọ rẹ lati ba a ran. Danladi ni inu iyara toun ati ọmọ naa wa ni ọmọ ọhun ti n ṣẹwọ soun, to n seju si oun, si n fọwọ pa oun lara ni awọn ibi ti ko daa, toun si kuku ṣe ifẹ inu rẹ fun un nigba toun ki i ṣe akura rara.

Alukoro ti ṣeleri pe gbara tawọn ba ti pari gbogbo iwadii awọn tan lori ọrọ Danladi lawọn maa foju rẹ bale-ẹjọ, ko le lọọ fimu kata ofin.

 

Leave a Reply