Oludasilẹ ileeṣẹ redio ati tẹlifiṣan AIT, Oloye Raymond Dokpesi ti jade laye.
Ọsibitu kan niluu Abuja ni wọn ni ọkunrin naa naa dakẹ si. Ọkunrin oloṣelu to jẹ ọkan ninu awọn agba ẹgbẹ PDP yii la gbọ pe o ṣe diẹ to ti ni aisan rọpa-rọsẹ, eyi ti wọn ni ọkunrin naa ti n gba itọju le lori ko too waa pada jade laye laaarọ kutukutu lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un yii.
Ẹni ọdun mọkanlelaaadọrin ni kọlọjọ too de.
Awọn iyawo, ọmọ ati ọmọọmọ lo gbẹyin ologbe naa.