Monisọla Saka
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorilẹ-ede Naijiria, Nigerian Labour Congress, (NLC), ti fi atẹjade sita lori bi iyanṣẹlodi wọn yoo ṣe lọ, ati idi ti wọn ṣe fẹẹ gun le e. L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni wọn lawọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi ọhun nitori owo iranwọ ori epo tijọba Tinubu yọ, eyi to ti ṣokunfa bi owo mọto atawọn nnkan mi-in ṣe gbowo lori gegere.
Lati ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, iyẹn lọjọ ti wọn bura wọle fun Aṣiwaju Bọla Tinubu gẹgẹ bii Aarẹ Naijiria tuntun lo ti sọ ọ ninu ọrọ ẹ pe ko sohun to n jẹ owo iranwọ ori epo mọ lati apo ijọba, latigba naa ni epo ti di ọwọngogo, tawọn nnkan mi-in naa si ti gbowo lori.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ti kọkọ fa ijọba leti pe awọn yoo gun le iyanṣẹlodi, lẹyin tawọn igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa jokoo ipade niluu Abuja.
Ninu iwe atẹjade yii ni wọn ti mẹnu ba awọn idi pataki kan, tawọn fi gbọdọ maa woṣẹ niran lai ṣe. Wọn ni pẹlu owo iranwọ ti wọn n san yii naa, ijọba Naijiria atawọn ti wọn wa nipo aṣẹ, agaga nileeṣẹ epo rọbi orilẹ-ede yii (NNPC), ko ṣai maa jẹ ajẹbanu, ti wọn si n fi owo iranwọ ṣe bojuboju.
Gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ naa, Joe Ajaero ṣe sọ ninu atẹjade toun ati Akọwe ẹgbẹ naa, Emmanuel Ugboaja, fọwọ si, ni wọn ti sọ pe ohun to mumu laya awọn ju ni ti wahala, iya ati idaamu ti ọrọ epo to gbowo leri latari owo iranwọ ti wọn yọ kuro n fa fawọn ọmọ Naijiria.
Akọkọ ni pe, wọn ni iwa irufin nijọba apapọ hu pẹlu bi wọn ṣe kede yiyọwo iranwọ ori epo.
Ẹlẹẹkeji si ni pe ninu iwe aba eto iṣuna ọdun 2023 yii, ti wọn ti ṣeto ẹ latọdun to lọ, ijọba apapọ ni lati sanwo iranwọ titi di ipari oṣu Kẹfa, ọdun ni, dipo oṣu Karun-un ti wọn kede pe awọn ko ṣe mọ.
Wọn tẹsiwaju pe ijọba ko wo ti inira ati idaamu ti igbesẹ wọn le ko ba awọn oṣiṣẹ ati araalu, bẹẹ ni wọn ko wa ọna abayọ silẹ ti wọn fi yọwọ yọsẹ ninu ọrọ owo iranwọ. Wọn lawọn pẹlu ijọba ti n sọrọ, awọn si ti fẹnu ọrọ ti sibi kan ki wọn too gbẹyin lọọ kede pe awọn ko sanwo iranwọ mọ.
Wọn ni idi karun-un ni pe gbogbo awọn ibudo ifọpo mẹrẹẹrin to jẹ tijọba ni wọn ti dẹnu kọlẹ, nigba tijọba ko nawo si i, ti wọn o si fi taratara ya si i mọ.
“Ẹlẹẹkẹfa ni pe, ‘‘A ko fara mọ afikun iye owo tuntun ti wọn n ta epo mọ, titi digba ti wọn yoo fi maa fọ epo nileeṣẹ ilẹ wa gangan’’.
Bakan naa ni wọn ni imọ-tara-ẹni-nikan ni ipinnu tijọba ṣe yii, nitori idajọ kootu kan wa to lodi si ki ijọba maa paṣẹ iye ti wọn gbọdọ maa ta epo lorilẹ-ede yii”.
Wọn fi kun un pe ki ileeṣẹ NNPC jade, ki wọn waa sọ ohun ti wọn ri, to si fa abajade iye owo epo tuntun ti wọn kede, ki wọn si ṣalaye awọn ti owo iranwọ n de si lọwọ tẹlẹtẹlẹ fawọn.
Ẹgbẹ oṣiṣẹ ni ohun to le mu ki ọrọ wọ laarin awọn pẹlu ijọba ni pe ki wọn da owo epo pada si iye to wa tẹlẹ, ni ibamu pẹlu ohun to wa ninu aba eto iṣuna ọdun 2023. Ati pe ọjọ meje tawọn fi silẹ lati fa wọn leti ti bẹrẹ lati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ti wọn o ba ti waa wa ojutuu si ọrọ to wa nilẹ, laaarọ kutukutu Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lawọn yoo bẹrẹ iwọde ifẹhonu-han ati iyanṣẹlodi, tawọn ko ti i mọ igba ti yoo pari.