Adewale Adeoye
Ni bayii, awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Eko ti fun gbajumọ aṣere tiata ilẹ wa nni, Iyabọ Ojo, lọjọ meje pere lati fi san gbese miliọnu mejidinlogun Naira, ajẹsilẹ owo-ori rẹ niluu Eko, tabi ki wọn fọwọ ofin mu un bo ba kọ lati sanwo naa bọjọ ti wọn fun un ba pe.
Lori ikanni Instagraamu oṣere yii lo gbe aworan lẹta ti wọn fi beere owo-ori yii si.
ALAROYE gbọ pe owo ọdun meji sẹyin ni awọn alaṣẹ to n ri sọrọ owo-ori ọhun ṣi papọ, ti wọn si sọ pe miliọnu mejidinlogun ni owo ti oṣere naa gbọdọ san s’apo ìjọba Eko.
Ṣugbọn oṣere yii ni ala ti ko le ṣẹ ni owo ti wọn n beere lọwọ oun yii. Iyabọ Ojo ni ko sohun to jọ ọ rara. O waa pe awọn olowo-ori naa nija pe ki wọn waa ṣalaye ọja ti oun n ta ati ere toun n jẹ lori rẹ toun yoo fi san owo to to bẹẹ gẹgẹ bíi owo-ori.
Ohun tawọn alaṣẹ ijọba Eko ti wọn n ṣe iṣiro owo-ori fawọn araalu Eko sọ ni pe lọdun 2012, o yẹ ki Iyabọ Ojo san miliọnu mọkanla Naira, nigba to yẹ ko san miliọnu meje Naira lọdun 2022 to kọja yii. Apapọ rẹ ni wọn pe ni gbese owo-ori ti Iyabọ Ojo jẹ awọn alaṣẹ ijọba Eko bayii. Ti wọn si fun un ni ọjọ meje pere tabi kawọn fọwọ ofin mu-un pe o tapa sofin ilu Eko.
Ninu atẹjade kan bayii ti Iyabọ Ojo gbe jade lori ẹrọ ayeluara rẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, lo ti fara ya gidi, to si n sọrọ sawọn aṣoju ijọba Eko ti wọn gbe owo nla naa wa fun UN gẹgẹ bii owo-ori to maa san.
Iyabọ Ojo ni, “Mi o mọ ohun ti wọn ro papọ ti wọn fi sọ pe, ki n waa san aduru owo to to’yẹn o, mo n bẹ wọn ni pe ki wọn waa sọ awọn ohun ti wọn ro papọ fun mi ti wọn fi sọ pe, ki n waa sanwo-ori to to yii. Wọn ti figba kan naa pe mi lọfiisi wọn tẹlẹ nipa ọrọ owo-ori yii, mo lọ sọdọ wọn, mo si ṣalaye awọn okoowo mi fun wọn ati iye owo ti mo n ri lojoojumo, ki i ṣe emi nikan ni mo lọ paapaa, mo mu ọkan lara awọn to n ba mi ri sọrọ owo-ori dani lọjọ naa. Bẹẹ la si pari gbogbo ọrọ naa lọjọ ọhun, bi wọn ṣe tun waa sọ pe mo jẹ aduru owo yii gan-an lo n ya mi lẹnu bayii.
“Ẹ ni ki wọn waa sọ bi wọn ṣe ṣeṣiro wọn, ti won fi sọ pe mo n jẹ to miliọnu mejidinlogun. Ki gan-an ni mo n ta niluu Eko paapaa, ṣe o ju ibi kan ṣoṣo ti mo ti n ṣọrọ aje mi lọ yii ni, ati ile kan ti mo n gbe. Emi o lowo kankan ti ma a san o, afi ti wọn ba fẹẹ pa mi nikan lo ku.
“Mo kuku n sanwo ori kọọkan lori awọn okoowo mi fun wọn, o ṣe waa jẹ pe ẹni kan a kan wa lọfiisi rẹ ninu ọyẹ, ta a si sọ pe ki wọn maa fiya jẹ awọn araalu bo ti ṣe wu u.
“Ki tiẹ gan-an nijọba Eko atawọn to n ṣakoso rẹ ti ṣe fun mi paapaa ti wọn fi fẹẹ gba aduru owo-ori yii lọwọ mi. Funra mi ni mo ran awọn ọmọ mi lọ sileewe Lai si iranlọwọ ijọba. Gbogbo awọn ohun amayedẹrun to yẹ keeyan gbadun ko si nibẹ. Mi o ni i sanwo kankan fun ẹnibọdi.’ Bẹẹ ni Iyabọ Ojo sọ.
Latigba to ti gbe ọrọ yii sori Instagraamu rẹ ni awọn eeyan ti n sọrọ lori rẹ. Ijọba Eko atawọn to n gbowo-ori ni wọn si di ọpọ ẹbi owo gegere ti wọn n gba lọwọ àwọn araalu ru. Wọn ni ijọba ko faaye sílẹ fun awọn olokoowo keekeeke lati gberu pẹlu obitibiti owo-ori ti wọn maa n ṣẹ si wọn lọrun, leyii to jẹ pe ọpọ wọn ko jẹ ere to sun mọ owo-ori ti wọn n beere yii. Wọn ni koda, owo tẹlomi-in fi n ṣowo ko to owo-ori ti wọn maa n ni ki wọn san.
Awọn mi-in to tun sọrọ bu ẹnu atẹ lu ijọba Sanwoolu, wọn ni wọn kan n fi ikanran mọ Iyabọ ni, nitori pe ko ṣatilẹyin fun ẹgbẹ wọn lasiko ibo to kọja.
Ju gbogbo rẹ lọ, ijọba Eko lawọn yoo ti Iyabọ mọle bi ko ba sanwo, oṣere yii ni ko s’ibi toun ti fẹẹ ri iru ọwọ bẹẹ. Ko ti i sẹni to mọ’bi ti ọrọ naa yoo yọri si.