Nitori ẹsun pe o n ṣẹgbẹ okunkun, Kwara Poli gba iwe-ẹri akẹkọọ wọn kan pada 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn alaṣẹ ileewe gbogbonise tipinlẹ Kwara, Kwara State Polytechnic, ti kede lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa yii, pe awọn ti gba iwe ẹri HND, akẹkọọ wọn kan,  AbdulRasheed Zubair Ọlatunji. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o n sẹgbẹ okunkun, eyi to ta ko ibura to ṣe nigba ti wọn gba a si ileewe ọhun.

Ninu atẹjade kan ti Igbakeji akọwe agba ileewe ọhun, Ọgbẹni Ọlayẹmi Ọlatọni, gbe jade, eyi to tẹ ALAROYE lọwọ ni wọn ti sọ pe igbesẹ naa waye lẹyin abajade iwadii kan ti igbimọ oluwadii ileewe naa se lori ẹsun ẹgbẹ okunkun siṣe ti wọn fi kan an.

Wọn ni Abdurasheed lọwọ ninu ẹgbẹ okunkun ṣiṣe, eyi to ta ko iwa ọmọluabi ati agbekalẹ eto ti ileewe naa tori ẹ fun un niwee-ẹri. Bakan naa lawọn alaṣẹ ileewe yii lawọn ko ni i forukọ rẹ ṣọwọ si ajọ agunbanirọ, eyi ti ko ni i fun un lanfaani lati sin orile-ede baba rẹ.

Leave a Reply