Adewale Adeoye
Ni bayii, adajọ ile-ẹjọ giga kan niluu Eko, Onidaajọ Chukwuejekwu Aneke, ti ni ki Ariyibi Ọlaṣẹinde, ẹni ọdun mọkandinlaaadọta lọọ lo ọdun marun-un ni ọgba ẹwọn pẹlu iṣẹ aṣekara.
Ẹsun ti wọn fi kan Ariyibi ni pe o fẹẹ gbe egboogi oloro, kokeeni, lọ sorileede Saudi Arabia. Ṣugbọn ọwọ ajọ to n gbogun ti lilo ati gbigbe egboogi oloro nilẹ wa, ‘National Drug Law Enforcement Agency’ (NDLEA), tẹ ẹ ni papakọ ofurufu kan to wa niluu Eko, l’ogunjọ, oṣu Keji, ọdun yii.
Nigba to n sọrọ ni kootu, ọlọpaa olupẹjọ, Augustine Nwagu, to foju Ariyibi bale-ẹjọ sọ pe ọwọ ajọ NDLEA tẹ Ariyibi ni papako ofurufu Murtala Mohammed International Airport, to wa niluu Eko, l’ogunjọ, oṣu Keji, ọdun yii, lakooko to fẹẹ gbera nilẹ yii lọ siluu Medina, lorileede Saudi Arabia, lati lọọ ta egboogi olori naa fawọn onibaara rẹ kan ti wọn ti n duroo de e lọhun-un.
Olupẹjọ naa sọ fun adajọ pe ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Jeleel Badmus, ni olujẹjọ ni o gbe oogun oloro naa ran oun, pẹlu ileri pe oun yoo fun oun ni
ẹgbẹrun kan aabọ dọla ($1,500), boun ba le gbe egboogi naa lọ silẹ Saudi yii. Ọọdunrun dọla ($300), ni ọkunrin naa ti sa fun olujẹjọ yii ninu owo ti wọn jọ ṣadehun.
Agbefọba ni ni kete ti ọkunrin to ran Ariyibi niṣẹ yii ti mọ pe ọwọ ti tẹ ẹ lo ti na papa bora, tawọn agbofinro si n wa a titi di ba a ṣe n sọ yii.
Nigba ti adajọ n beere lọwọ Ariyibi boya o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an yii, ọkunrin naa ni oun jẹbi, o si rawọ ẹbẹ si adajọ pe ko ṣiju aanu wo oun lori ọrọ naa.
Pẹlu ọrọ ti Ariyibi sọ yii, olupẹjọ rọ adajọ naa pe ko yẹ iwe ofin ilẹ wa wo lati fi ṣedajọ to yẹ fun Ariyibi.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Chukwuejekwu Aneke ran Ariyibi lẹwọn ọdun marun-un pẹlu iṣẹ aṣekara, tabi ko san miliọnu marun-un Naira gẹgẹ bii owo itanran. Bakan naa ni wọn ni ki Ariyibi ṣiṣẹ ogoje wakati laarin ilu, ki wọn si tun gba ọọdunrun dọla owo ilẹ okeere to gba lọwọ Badmus ati iwe irina rẹ lati lọ soke okun lọwọ rẹ.
O ni yoo le jẹ ẹkọ nla fawọn yooku ti wọn ba tun fẹẹ gbe egboogi oloro lọjọ iwaju.