Emi gan-an fara mọ yiyọ owo iranwọ epo bẹntiroolu, ṣugbọn… Peter Obi

Adewale Adeoye

Oludije dupo aarẹ orileede yii lẹgbẹ oṣelu ‘Labour Party’ (LP), Ọgbẹni Peter Obi, ti sọ pe oun paapaa fara mọ aba lati yọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu tawọn alaṣẹ ijọba akoko yii pinnu lati yọ, ṣugbọn ọna ti wọn gbe kinni naa gba lo ku diẹ kaato.

Obi sọrọ ọhun di mimọ lori ẹrọ ayelujara abayẹfo Tuita rẹ lọjọ Iṣẹgun, Tuisdee, ọjọ kẹfa, oṣu Kefa, ọdun 2023 yii. O sọ pe ọpọ eeyan ni wọn n sọ pe ki oun sọrọ lori bi wọn ṣe yọ owo iranwọ epo bẹntiroolu kuro, eyi to ti n mu inira ba awọn araalu pẹlu bi epo ṣe gbowo lori. Ọkunrin naa ni latigba iṣakooso ijọba Jonathan, toun si ba a ṣiṣẹ lẹka to n mojuto ọrọ aje ilẹ wa. O ni latigba naa loun ti kọminu si bi ijọba ilẹ yii ṣe n san owo iranwọ lori epo bẹntiroolu, nitori ki i ṣe ohun to daa rara, ipalara ti ko lẹgbẹ ni igbesẹ yii si n fa fun ọrọ aje ilẹ wa ni gbogbo ọna gẹgẹ bo ṣe sọ.

Obi ni, ‘Bẹ ẹ ba woye daadaa, ẹ maa ri i pe emi paapaa ko fara mọ bawọn alaṣẹ ijọba ilẹ wa ṣe n sanwo iranwọ lori epo bẹntiroolu yii rara. Latigba ijọba Jonathan ti mo ba ṣiṣẹ gẹgẹ bii ọmọ igbimọ ọrọ aje ilẹ wa ni mo ti n kigbe naa fawọn alaṣẹ pe awọn kan ni wọn ko ara wọn jọ, ti wọn n ko owo naa da sapo. Mo sọ nigba naa pe awọn ọmọ orileede wa ko lo to iye lita epo bẹntirolu ti wọn n kede pe a n lo yẹn rara, jibiti ni wọn n fọrọ epo naa lu orileede wa.

Ṣugbọn bo tilẹ jẹ pe gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ naa fọwọ si ki wọn yọ owo iranwọ epo ọhun, ọkunrin yii ni ọna ti ijọba to wa nita yii gbe e gba ku diẹ kaato. Obi ni bo ba jẹ pe oun loun wa nipo aarẹ orileede yii ni, ki i ṣe ọna toun maa gbe ọrọ yiyọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu naa gba niyi. Ọkunrin naa fi ọrọ iranwọ epo yii we ẹni to lọ sọdọ dokita to n yọ eyin. O ni ẹni ti eyin n dun, ti tọhun si lọ sọdọ dokita eleyin lati yọ ọ, ti dokita naa si fi awọn oogun kan si ọgangan ibi to ti fẹẹ yọ eyin ohun, eyi ti ẹni to fẹẹ yọ eyin rẹ ko fi ni i mọ ala pe o yọ eyin naa, o ni itura lo maa wa fun ẹni to yọ eyin, ko si ni i fi bẹẹ mọ inira kankan.

Obi ni ṣugbọn ki eyin maa dun-un-yan, ko lọ sọdọ dokita, ki tọhun si ki eroja kan mọlẹ, ko fa eyin naa tu puru, inira ti yoo tidi rẹ yọ ko ni i ṣe e fẹnu sọ, o fi igbesẹ ti ijọba gbe lori bi wọn ṣe yọ owo iranwọ naa lai jẹ ki wọn pese ọna ti itura yoo fi wa faraalu silẹ ko bojumu to.

Oludije sipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ Labour yii sọ pe to ba jẹ oun loun wa lori aleefa, ọna ti dokita akọkọ, iyẹn dokita to ti kọkọ fi oogun ti ko ni i jẹ ki ẹni ti eyin n dun mọ inira ki oun too yọ ọ loun maa lo.

Bẹ o ba gbagbe, lati ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii ti ijọba Bọla Tinubu ti kede pe oun yoo yọ owo iranwọ epo bẹntiroolu lawọn ile-epo kaakiri orileede yii ti fi owo kun iye ti wọn n ta jala epo kan, eyi to ti fa inira nla fawọn araalu.

Leave a Reply