Adewale Adeoye
Titi di akoko ta a n ko iroyin yii jọ, inu ọfọ nla gbaa ni gbogbo ẹbi atawọn ọrẹ akẹkọọ kan, Oloogbe Ayomide Oduntan, to jẹ akẹkọọ Fasiti Afẹ Babalọla, to wa niluu Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, wa bayii. Eyi ko sẹyin iku ojiji to mu ẹmi ọmọ naa lọ lai jẹ pe o ṣaisan tẹlẹ. Bo ṣe pari idanwo aṣekagba rẹ tan nileewe naa ni won lo ṣubu lulẹ, to si ku patapata ki wọn too gbe e de ọsibitu kan to wa ninu ọgba ileewe naa fun itọju rara.
ALAROYE gbọ pe ko ju wakati meloo kan lọ lẹyin ti Ayọmide pari idanwo aṣekagba rẹ tan, to si n dunu pe oun kẹkọọ pari nileewe naa lo ṣubu lulẹ, to si ku. Ohun to jẹ kọrọ iku rẹ dun awọn ololufẹ rẹ pupọ ni pe ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 yii, ni Ayọmide loun maa ṣayẹyẹ ọjọọbi ọdun mọkanlelogun toun dele aye, to si ti n ṣegbaradi awọn eto ti yoo mu ki ayajọ ọjọ naa dun daadaa fun gbogbo awọn alejo pataki to fẹ fiwee pe, lai mọ pe ko ni i duro ṣọjọọbi naa.
Ọgbẹni Wale Saliu to jẹ ọkan pataki lara awọn mọlẹbi ọmọkunrin yii sọ pe, ‘‘Kayeefi nla gbaa lọrọ iku to pa Ayọmnide ṣi jẹ fun gbogbo wa pata, a ko gbọ lati ẹnu ẹnikankan tẹlẹ pe o n ṣaisan, iroyin iku rẹ la kan deede gbọ lati ileewe rẹ. Koda, Ayọmide pe mama rẹ, o si ba a sọrọ ni gbara to pari idanwo rẹ tan. Lojiji si ni ọkan lara awọn ọrẹ rẹ pe mama yii pada, to si tufọ iku ọmọ Ayọmide fun un lọjọ keji. Gbogbo wahala wa lori Ayọmide ti ja sasan bayii, gbogbo owo ta a na le e lori ti wọmi patapata.
Lori iṣẹlẹ iku akẹkọọ yii, Alukoro ileewe ọhun, Ọgbẹni Tunde Ọlọfintoto paapaa ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin. O sọ pe, ṣe ni omokunrin to ṣẹṣẹ pari idanwo to gbẹyin fun un nileewe ọhun deede ṣubu lulẹ lojiji, to si ku ko too di pe wọn gbe e de ọsibitu kan to wa ninu ọgba ileewe naa. O ni gbogbo akitiyan awọn dọkita lati doola ẹmi rẹ lo ja si pabo.