Oṣere tiata tun bimọ fun Portable olorin zah zuu

Monisọla Saka

Ọkunrin olorin hip hop tawọn ọdọ isinyii n ko jẹ nigboro, Habeeb Okikiọla ọmọ Ọlalọmi, tawọn eeyan mọ si Portable tabi Zaazuu, ti tun di baba ikoko mi-in, lẹyin ti ololufẹ ẹ kan to jẹ osere tiata, Akinyanju Ọmọbọlarinde, bimọ ọkunrin fun un lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.

Portable to jẹ pe iyawo ile ẹ ti bimọ meji, to si tun ti lọmọ meji mi-in lọdọ obinrin ọtọọtọ, ni eyi to ṣẹṣẹ bi yii yoo jẹ  ẹlẹkaarun-un to tun wọle tọ ọ wa.

Funra iya ọlọmọ, iyẹn Ọmọbọlarinde, lo gba ori Instagraamu lọ, nibẹ lo gbe oriṣiiriṣii fọto ara ẹ ati tọmọ tuntun naa pẹlu baba ikoko si.

Bakan naa lo gbe aworan ikun ẹ to yọ bọbọ lasiko to wa nipo iloyun si i. O si kọ ọrọ sibẹ bayii pe, “Ọlọrun ti ṣe ohun to pọ fun wa to jẹ pe mi o le sọ ọ tan. Oluwa O ṣe e fun irinajo latigba yii wa, inu mi dun lati darapọ mọ awujọ awọn ọlọmọ.

Mo n pada bọ lati kọ oriṣiiriṣii ọrọ bo ṣe ti wa lọkan mi, ati ọrọ idupẹ, nitori aaye ọpẹ yọ. Okikiọla mi, ku oriire. Emi Ashabi simple naa kira mi ku oriire. Ọlọrun a ba wa bu kun fun ọmọ naa, Yoo si ba wa daabo bo Anuoluwapọ Fitilamihan fun wa.

Ọba mi-in to daye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti tun wọnu ẹbi Badmus. Ọba lo n bi ọba. Ilu awọn ọba ree, Akoi King Nation.

Ọpọlọpọ eeyan lo ti n ki obinrin yii ati Portable ku oriire ayọ nla ti Ọlọrun ṣe fun wọn ọhun. Awọn ololufẹ Portable mi-in tilẹ tun sa ori ẹ, wọn lawọn ṣẹṣẹ bẹrẹ ni.

Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ loju awọn ẹlomi-in, wọn ni ki i ṣe gbogbo obinrin lo lojuti, ti wọn gbọn, ti wọn si loju inu, nitori ko sohun ti wọn ko le la itan fun to ba ti ba owo de.

Awọn ẹlomi-in si ki i nilọ lati ṣọra fobinrin, koun naa ma baa di 2face ojiji, ati pe owo to wa lọwọ ẹ lawọn obinrin ṣe n dooyi yi i ka.

Leave a Reply