Monisọla Saka
Ẹgbẹ awọn ọmọ bibi ilu Ekiti kan, Ekiti Patriotic Consultative Forum (EPCF), ti gba gomina ana nipinlẹ naa, Kayọde Fayẹmi, nimọran lati da owo ilu to to biliọnu lọna ogun Naira (20 billion), ti wọn fẹsun ẹ kan an pe o ko jẹ pada ni kiakia.
Wọn ni owo to yẹ ki wọn fi ṣe nnkan daadaa sinu ilu ti Fayẹmi ko da sapo ara ẹ lawọn n rọ ọ lati jade waa sọ bo ṣe rin, tabi ko tilẹ da gbogbo owo to ji ko ọhun pada.
Ṣaaju akoko yii ni awọn ẹgbẹ yii ti kọwe si ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorilẹ-ede yii (EFCC), lati fofin gbe gomina tẹlẹri ọhun, ki wọn si bi i leere ibi to ko owo ilu to yẹ ki wọn fi kọ papakọ ofurufu ti wọn yoo maa kẹru si atawọn iṣẹ akanṣe nla mi-in si.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lawọn ẹgbẹ naa fi atẹjade kan lede, apa kan rẹ ka bayii pe, “A ti gbọ si atẹjade kan ti ọkunrin kan ti wọn n pe ni Ahmad Sajoh fi sita, a o si sọrọ lori abuku to fi kan ẹgbẹ wa pẹlu bo ṣe ni a ko ja mọ nnkan kan. Ṣugbọn fun un lati mọ bi a ṣe ṣe pataki to, Akọwe ẹgbẹ wa, to tun jẹ agbẹjọro, Gbenga Babawibẹ, lo buwọ lu iwe ẹsun ti wọn kọ ta ko Dokita Fayẹmi.
‘‘Awọn eeyan pataki ti idagbasoke ipinlẹ Ekiti jẹ logun lawọn ọmọ ẹgbẹ wa. A o si ni i gba ki wọn fi ifọrọwanilẹnuwo ti ajọ EFCC n ṣe fun Fayẹmi lọwọ yii ṣe ọrọ inu iroyin nikan, bẹẹ la o ni i gba ki wọn tun lo ọrọ abuku lati fi ṣapejuwe ẹgbẹ wa mọ ninu atẹjade wọn mi-in”.
Wọn ni lara iwa to n fi ipo aṣiwaju mulẹ ni keeyan ṣalaye bi owo ati gbogbo nnkan ṣe rin ti wọn ba pe e, ati lati ni iwa akin lati le sọ bi wọn ṣe nawo kọọkan nigba ti wọn wa nipo agbara, yatọ si ki wọn maa sare gba ori ayelujara lọ lati wẹ ara wọn mọ lori irọ, tabi biba ọmọlakeji lorukọ jẹ.
Ẹgbẹ ti ọkunrin kan to n jẹ Ahmad Sajoh, jẹ adari wọn ni wọn ti kọkọ pe ẹgbẹ to pe Fayemi nija lati da owo Ekiti pada yii ni aja inu iwe ti ko le bu ni jẹ, wọn ni wọn ko ri egbo walẹ. Orọ ti wọn sọ yii ni EPCF fesi si, nitori wọn gbagbọ pe ọkan ninu awọn eeyan Fayẹmi lo kọ ọ.