Wọn ti dajọ iku fun pasitọ ijọ to pa ọmọ ẹgbẹ akọrin ṣọọṣi rẹ to fun loyun

Adewale Adeoye

Iku ni ere ẹṣẹ gẹgẹ bi ọn ṣe maa n sọ, ere agbere ati iwa ika pẹlu yikun yikun iṣẹju diẹ ti mu ki adajọ ni ki wọn lọọ yẹgi fun pasitọ kan to ba ọkan ninu aọn ọmọ egbẹ akọrin ijọ rẹ lo pọ, to si tun ṣeku pa a. Onidaajọ S.O Benson ti ni ki wọn pa ọkunrin naa, ko si maa lọọ ṣalaye ohun to mu ko pa ọmọbinrin naa fun un nigba ti wọn ba rira wọn.

Adajọ ile-ẹjọ giga kan niluu Port-Harcourt, nipinle Rivers, lo dajọ iku fun Pasitọ Okoroafor Chidiebere, ti ijọ Ọlọrun kan ti wọn n pe ni ‘Altar Of Solution And Healing Assembly’, to wa lagbegbe Oyigbo, niluu Port-Harcourt. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe ṣe lo pa ọkan lara awọn ọmọ ijọ rẹ to jẹ akọrin ninu ṣọọṣi rẹ, Oloogbe Orlunma Nwagba, lẹyin ti fun un loyun tan.

ALAROYE gbọ pe Okoroafor pinnu lati pa ọmọ ijọ rẹ yii ni gbara ti awo ọrọ ọhun ti fẹẹ lu sita, ti ko si fẹ kawọn ọmọ ijọ yooku mọ ohun to n ṣẹlẹ laarin ohun ati omọbinrin naa.

Wọn ni Abilekọ kan, Chigozie Ezenwa, to jẹ ọrẹ oloogbe naa ati ọmọ oṣu mọkanla kan, Cresable, to n tọju lọwọ ni Okoroafor tun pa danu pẹlu ale rẹ naa nitori pe wọn mọ nipa ọrọ yii.

Ọjọ kọkanla, oṣu Kejila, ọdun 2017, ni Okoroafor hu iwa ọdaju naa,  ọkọ Oloogbe Ezenwa lo lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ti wọn si lọọ fọwọ ofin mu un nile.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ S.O Benson ni ko si awijare kankan fun Okoroafor rara, o ni o jẹbi awọn ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an. Ko si fi akoko ṣofo rara to fi paṣẹ pe ki wọn lọọ   yẹgi fun un titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ.

O ni yoo jẹ ẹkọ nla fawọn yooku ti wọn fẹẹ hu iru iwa ọdaju ti ọkunrin to pera ẹ niranṣẹ Ọlọrun yii hu lawujọ wa.

Bakan naa ni agbẹjọro to n soju fun ijọba ipinlẹ naa lori ọrọ ọhun, Lọọya Precious Ordu, dunnu si bi idajọ naa ṣe lọ, to si gboṣuba nla fun adajọ naa bo ṣe ni igboya nla lati dajọ iku fun Pasitọ Okoroafor.

Leave a Reply