Ọwọ tẹ ole ajifoonu to mura bii alaamojuto idanwo ni Fasiti Ifẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ahesọ to kọkọ n lọ kaakiri ni pe alaamojuto idanwo (Invigilator) ni ọkunrin ti ọwọ awọn akẹkọọ Fasiti Ifẹ tẹ laipẹ yii lori ẹsun ole jija.

Ṣugbọn ninu atẹjade kan ti Alukoro ileewe ọhun, Abiọdun Ọlarewaju, fi sita lọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lo ti ṣalaye pe ọkunrin ti wọn n pariwo ole le lori ninu fọnran naa ki i ṣe olukọ, bẹẹ ni ki i ṣe akẹkọọ fasiti naa.

Ọlarewaju ṣalaye pe ṣe ni afurasi naa mura daadaa bii olukọ, ti ko si sẹni to fura si i pe ki i ṣe olukọ nigba to wọnuu kilaasi kan ti awọn akẹkọọ ti n ṣedanwo.

O ni bo ṣe ri i pe idanwo ti wọ awọn akẹkọọ naa lara lo bẹrẹ si i ki ọwọ bọ inu baagi wọn lẹyọkoọkan, nibi ti wọn da a jọ si.

Eleyii lo n ṣe lọwọ ti awọn akẹkọọ fi kẹẹfin rẹ, ti wọn si pariwo le e lori. Imura rẹ lo si jẹ ki wọn maa sọ kaakiri pe alamojuto idanwo (invigilator) ni.

ALAROYE gbọ pe ọmọkunrin naa ti ji to foonu mẹsan-an ki ọwọ too tẹ ẹ, awọn akẹkọọ si fa a le ọlọpaa inu fasiti naa lọwọ.

 

Leave a Reply