O ma ṣe o, ọfọ nla ṣẹ Saidi Balogun

Jọkẹ Amọri

Inu ibanujẹ nla ni oṣere ilẹ wa to ti tun mu oṣelu mọ iṣẹ rẹ bayii, Saidi Balogun, wa o. Bẹẹ lawọn ololufẹ rẹ atawọn oṣere ẹgbẹ ẹ ti n ki i ku irọju, ti wọn si n gbadura fun un ni kikankikan pe ki Ọlọrun tu u ninu, ko si dawọ ibi duro ninu mọlẹbi rẹ.

Aburo oṣere naa ti wọn jọ jẹ ọmọ iya kan naa lo ku lojiji. Bo tilẹ jẹ pe Saidi ko so ohun to fa iku obinrin to pe orukọ rẹ ni Idiat Balogun Aminu yii, awọn ọrọ to kọ fi han pe iku obinrin naa dun un gidigidi.

Lori Instagraamu rẹ lo gbe e si pe, ‘‘Ọlọrun, ọdọ rẹ la ti wa, ọdọ rẹ naa la maa pada si. Pẹlu ọgbẹ ọkan ni mo fi n ṣọfọ aburo mi ti mo nifẹẹ gidigidi, Idiat Balogun Aminu.

‘‘Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe mo pin inu kan naa pẹlu rẹ, tawa mejeeji ti jade, Idiat. Titi lae ni o maa wa ninu ọkan mi. Ma a sinmi lọ, aburo mi daadaa. Mo maa ṣafẹẹri rẹ gidigidi.

Latigba ti oṣere yii ti gbe ọrọ naa sori ikanni rẹ lori ayelujara ni awọn oṣere ẹgbẹ ẹ atawọn ololufẹ rẹ ti n ki i ku ara fẹra ku aburo rẹ to ku lojiji ọhun.

Lara awọn to ti ṣe Saidi ni pẹlẹ ni olorin waka nni, Salawa Abẹni, ẹni to kọ ọrọ sabẹ ohun ti Saidi kọ yii pe, ‘Haaa, Sidooo. Pẹlẹ o, aburo mi.’

Bakan naa ni Yẹmi Ṣolade ti ba oṣere yii kẹdun. Ninu ọrọ idaro to kọ si i lo ti sọ pe, ‘Ki Ọlọrun fun ọkan rẹ ni isinmi. Jọwọ, mu ọkan le. A o ni i ri atẹyinku mọ.

Bakan naa ni Yinka Quadri, Ṣeyi Ẹdun atawọn mi-in bẹẹ ti ki oṣere yii ku ara fẹra ku aburo rẹ, ti wọn si gbadura fun un pe Ọlọrun yoo tu u ninu.

 

Leave a Reply