Adewale Adeoye
Mọto olowo nla mẹrin (SUVs) to je ti ijọba ipinlẹ Zamfara lawọn agbofinro ti ko kuro nile gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Alhaji Bello Matawalle. Wọn ni nigba ti ọkunrin naa fẹẹ kuro nileejọba lo ko awọn mọto ọhun atawon ẹru ijọba mi-in lọ. Eyi lo mu ki ajọ to n ri si iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọku-mọku ‘Economic And Financial Crimes Commission’ (EFCC), lọọ fọwọ ofin ko wọn jade kuro ninu ile ọkunrin naa to wa ni GRA kan bayii, to wa lagbegbe Gusau, nipinlẹ Zamfara, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.
Gbara ti gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ naa, Ọgbẹni Dauda Lawal, ti bọ sipo aṣẹ nipinlẹ naa lo ti pariwo sita fawọn araalu pe gbogbo ẹru to wa nileejọba ni gomina to ṣẹṣẹ gbejọba silẹ ọhun ko lọ. Yatọ si mọto, wọn ni awon nnkan eelo ile bii firiiji, tẹlifiṣan bẹẹdi atawọn nnkan mi-in ni wọn ko kuro nile-ijọba, ti wọn si sọ gbogbo ile naa di koronfo.
Lawal ni ko sohun kankan mọ ninu ile ijọba ti Matawalle fi silẹ rara, o ni mọto mẹtadinlogun to jẹ ti gomina ati ti igbakeji gomina ipinlẹ naa ni gomina tẹlẹ yii ti ji ko sa lọ patapata. Igbesẹ yii buru jai, o si ku diẹ kaato lati sọ ẹru ijọba ipinlẹ naa di tara rẹ.
Atẹjade pataki kan ti Alukoro eto iroyin fun gomina ọhun, Ogbẹni Sulaiman Idris, fi sita fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii, ni gomina ọhun ti kilọ fun Matawalle pe ko da gbogbo ẹru to ji pada sile ijọba laarin ọjọ marun-un pere.
Ninu ọrọ rẹ, Gomina Lawal ni, ‘Ọjọ marun-un pere ni mi fun Matawalle pe ko fi da gbogbo dukia ijọba to wa lọwọ rẹ pada, bo ba kọ lati ṣe bẹẹ, ma a fọwọ ofin gba awọn ẹru naa pada lọwọ rẹ. ‘Gbogbo mọto to n lo lakooko to fi wa nipo iṣakooso ijọba ipinlẹ naa lo ji ko sa lọ bayii, to si n sọ pe dukia toun ni. Matawalle ji ẹru ijọba dori gaasi idana ati faanu inu yara, mi o ti i ri iru olori bii tiẹ ri laye mi o’.
Gomina ọhun waa rọ awọn araalu gbogbo pe ki wọn ma ṣe mikan rara, o ni gbogbo ohun to n jọ Matawalle loju to fi ṣiwa-hu laarin ilu loun maa da pada sile ijọba laipẹ ọjọ.
Siwaju si i, Lawal ni, ‘Awọn mọto olowo nla gbogbo bii: Toyota Lexus, Toyota Land Cruiser, Toyota Prado, Toyota Prado V4, Toyota Land Cruiser Bullet Proof 2021 ati Toyota Lexus 2021 Model, ni Matawalle loun fi owo ijọba to din diẹ ni biliọnu meji Naira ra fawọn olori ẹka oṣiṣẹ kọọkan, ṣugbọn a ko ri ẹyọ kan ninu awọn mọto ọhun mọ.
‘A ti kọ lẹta si Matawalle pe ko jọwọ gbogbo ẹru ijọba to wa lọwọ rẹ fun wa, bi bẹẹ kọ, a maa fọwọ lile mu ọrọ rẹ ni’.
Bẹ o ba gbagbe, ki Matawalle too fipo silẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ naa ni ajọ EFCC ti fẹsun iwa jibiti kan an, wọn ni o ko biliọnu lọna aadọrin Naira sapo ara rẹ, ti wọn si sọ pe gbara to ba ti fipo silẹ gẹgẹ bii gomina lawọn maa fọwọ ofin mu un lati waa sọ tẹnu rẹ lori owo naa.
Ṣugbọn Matawalle paapaa ju oko ọrọ lu Alaga EFCC, Ọgbẹni Bawa pe ko sohun to le fi oun ṣe, nitori pe alaga naa beere owo riba miliọnu meji dọla owo ilẹ okeere kan lọwọ oun toun ko si fun un lo ṣe n dukooko mọ oun bayii.