Adewale Adeoye
Titi di akoko ta a n ko iroyin yii jọ, inu ọfọ nla ni gbogbo ẹbi ati ọrẹ Oloogbe Ṣọla Ogungbe, ẹni ọdun mokanlelogoji, to jẹ ọkan lara awọn ọga banki igbalode kan ti wọn n pe ni ‘SEAP Micro-Finance Bank,’ to wa niluu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, wa bayii.
Ko sohun meji tinu wọn ko fi dun s’ohun to ṣẹlẹ yii ju bi Ṣọla ṣe gbẹmi ara rẹ nitori owo ele kan to ya awọn onibaara rẹ kan tawọn yẹn ko si da a pada fun un, eyi to ja si igbese nla fun un lẹnu iṣẹ rẹ.
ALAROYE gbọ pe owo ti Ṣọla ya awọn onibaara rẹ le ni miliọnu kan Naira, ṣugbọn ti awọn to ya lowo naa kọ lati da a pada fun un, nigba to si jẹ pe oun lọga, oun naa lo si tun ṣe atọna bi owo naa ṣe jade lapo ileeṣẹ naa ni awọn alaṣẹ ileeṣe ọhun fi sọ fun un pe ko wa gbogbo ọna lati da owo naa pada sileeṣẹ ọhun. Gbogbo ọna ati ọgbọn ti Ṣọla mọ lo da lati gbowo ọhun pada lọwọ awọn ẹni to ya a, ṣugbọn ti ko so eeso rere kankan, eyi si wa lara idi ti ọkunrin naa ko lọ sibi iṣẹ mọ. Ọkan lara awọn ọrẹ rẹ kan nibi iṣẹ lo pe e sori foonu, nigba ti foonu rẹ ko lọ lọjọ Wesidee, oṣe to kọja yii, ni onitohun ba tun pe foonu iyawo Ṣọla, to si sọ fun un pe awọn ko ri ọkọ rẹ nibi iṣẹ fun ọjọ meloo kan sẹyin bayii.
Nigba tiyawo pada dele to ni ki oun lọọ jiṣẹ fun ọko oun, oku rẹ lo ba nibi to ku si. Loju-ẹsẹ niyawo naa ti figbe ta, tawọn araale ti wọn wa nitosi si tete wa ba a lati ran an lọwọ.
Ọkan lara awọn ọrẹ timọ-timọ Oloogbe Ṣọla to gba lati ba awọn oniroyin sọrọ, ṣugbọn to loun ko fẹẹ darukọ ara oun sita sọ pe aṣiṣe nla gbaa ni Ṣọla ṣe nipa bo ṣe pa ara rẹ lori owo ti ko to nnkan.
Onitọhun ni, ‘Ko yẹ keeyan gbẹmi ara rẹ lori ohun ti ko to nnkan rara, Ṣọla iba ti sọ awọn ohun to n la kọja fun wa ko too di pe o gbe igbesẹ buruku to gbe yii, o ṣee ṣe ko ri aanu gba lati ọdọ ẹni kan lara awa ọrẹ rẹ, oun naa ko je bẹẹ nigba to wa laye, ẹlẹyinju aanu gidi ni. Inu mi ko dun rara nigba ti mo gbọ pe o gbẹmi ara rẹ nitori pe awọn kan jẹ ẹ lowo. Bo ba tiẹ ṣoniduuro fawọn kan, iyẹn ki i ṣohun toju ko ri ri kẹ’’.
Wọn ti gbe oku Ṣọla lọ siluu rẹ ti i ṣe Omu-Aran, nipinlẹ Kwara, lati lọọ sin in.