O ṣoju mi koro ( Apa Keji)

Bẹ ẹ ba ri Tinubu, ẹ kilọ fun un jare

Lara eebu tabi ẹsun ti wọn maa n fi kan awọn ọmọ Yoruba naa ni pe awọn ni wọn maa n ba ti ara wọn jẹ, wọn aa ni bi ẹni kan ba wa ni oke giga nilẹ Yoruba, funra Yoruba naa ni yoo ja a bọ. Ṣugbọn eyi ti awọn ọmọ Yoruba ti wọn wa loke giga fi n ṣe ara wọn lo maa n pọ ju. Nitori bi awọn naa ba jaja de ipo kan tan, niṣe ni wọn yoo maa ju ipakọ lukẹ, ti wọn yoo maa ṣe bii ẹni pe awọn nikan ni Ọlọrun da aye fun, tabi pe lẹyin awọn, ko tun si ẹlomiiran nile aye mọ. Yoruba koriira iwa igberaga, tabi iwa ta ni yoo mu mi, tabi iwa fifi ara ẹni jẹ gaba le wọn lori, beeyan ba ṣe bẹẹ, yoo kan abuku nigbẹyin ni. Ni ilẹ Yoruba, ohun ti eeyan n ṣe niyi naa ni yoo ṣe tẹ ti ko ba ṣọra. Ohun ti Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ṣe lọsẹ to kọja yii ki i ṣe ohun to dara, bi ko ba si tete jawọ ninu iru awọn iwa bẹẹ, ohun ti yoo sare sọ ọ di alabuku, ati eeyan ti ko ni i pada jẹ kinni kan loju awọn ọmọ Yoruba ni. Nibi ayẹyẹ igbade Ọba Oniru l’Ekoo, Ọọni wa nibẹ bi alejo pataki. Ṣugbọn bi Ọọni ti de ti gbogbo eeyan si dide lati yẹ ẹ si gẹgẹ bii olori ilẹ Oodua, Tinubu ko dide, o jokoo bii ẹni pe Ọọni ko jẹ kinni kan, tabi pe oun ni ọga Ọọni. Bi kinni kan ba wa ti Yoruba koriira ju, oun naa ni ki a foju pa aṣa wọn rẹ, tabi ki a sọ pe aṣa wọn ko jẹ nnkan kan. Ẹnikẹni to ba n ṣe bẹẹ, bo ti wu ki ipo ẹni naa to, yoo di alabuku niwaju wọn gbẹyin ni. Ẹni ti Tinubu ri nibi igbade Oniru yẹn ki i ṣe Adeyẹyẹ Ẹnitan, Ọọni Ile-Ifẹ, nibi ti gbogbo Yoruba ti ṣẹ wa ni. Ọwọ yoowu ti Tinubu ba fun Ọọni nibẹ yẹn, ki ṣe Ẹnitan lo fun, gbogbo  Yoruba pata ni. Lati waa fi gbogbo Yoruba wọlẹ bi ọkunrin oloṣelu yii ti ṣe yii, nnkan ti ko daa gbaa ni. Bo ba jẹ oun lo fi Adeyẹye jẹ Ọọni bi awọn kan ti wi, laarin oun ati Adeyẹye ni, ki i ṣe laarin oun ati Ọọni Ifẹ, bo ba si jẹ Adeyẹye ti n gba owo lọwọ rẹ nigba kan ri, tabi ko maa tọrọ nnkan lọwọ rẹ ko too di ọba, laarin oun ati ẹ ni, ki i ṣe laarin oun ati Ọọni. Ti Yoruba l’Ọọni, ẹnikẹni to ba si ri i fin, idajọ afojudọba ni wọn yoo da fun un, awowo yoo wo o gbẹyin ni. Bi awọn oloṣelu Yoruba ti ri nu-un, gulegule ati agbara odi a maa gun wọn, bẹẹ wọn ko je kinni kan ju oṣelu odi ti a n ṣe nilẹ yii lọ o. Bi Tinubu yii kan naa ba lọ si ilẹ Hausa, ko jẹ bọ Sultan Ọba Ṣokoto lọwọ o, yoo di ẹṣẹ kuduru ti yoo ba buruburu mọlẹ ni, ṣugbọn o bọ si inira fun un lati dide fun Ọọni tiwa. O si fẹẹ di aarẹ o, o n fẹ ibo ọmọ Yoruba laipẹ rara. Oju gbogbo wa naa ni yoo ṣe. Ṣugbọn eyin ti ẹ ba sun mọ ọn, ẹ kilọ fun un daadaa o, nilẹ Yoruba nibi, arọbafin loba i pa, koda ko jẹ oloṣelu aye ju bẹẹ lọ!

 

Ẹyin gan-an lẹ fẹẹ ko ba a

Awọn kan wa nilẹ yii ṣaa to jẹ bi Tinubu yagbẹ sara, wọn yoo ni awọn ko gbooorun, bo n tọ silẹ, wọn yoo ni ko ṣe nnkan kan, bo ba si rinhooho paapaa, wọn yoo ni aṣọ to dara ju lọ lo wọ sọrun ni. Bẹẹ ni ki i ṣe pe wọn fẹran ọkunrin yii o, nitori ijẹkujẹ ti wọn n ri jẹ nitosi ẹ, tabi nitori oore ti wọn ro pe o n ṣe fawọn ti wọn mọ ni. Koko kan ti kaluku gbọdọ mọ ni pe Tinubu ki i ṣe oniṣowo, bẹẹ ni ko da ileeṣẹ kan to ga rẹpẹtẹ silẹ, iṣẹ okoowo kan naa to ni, oṣelu ni, ẹni to ba si ni iru iṣẹ bayii, ẹrusin araalu ni, ilu lo yẹ ko maa sin, ko yẹ ko gberaga si awọn to niluu ọhun nibikibi. Bi wọn ti n ṣe oṣelu niyẹn. Awọn oloṣelu ilu oyinbo ko ni i ri mẹkunu fin, koda ko jẹ ọmọ kekere adugbo wọn. Ko si iranlọwọ meji ti gbogbo awọn ti wọn ba fẹran Tinubu le ṣe ju ki wọn ba a sọ ootọ ọrọ nigba to ba ṣe aṣiṣe lọ, bo ba si ṣe aṣiṣe ti ko ba mọ pe aṣiṣe loun ṣe, awọn ololufẹ rẹ lo yẹ ki wọn sọ fun un pe aṣiṣe leyi to ṣe yii, ko ma tun ṣe bẹẹ mọ, tabi ko tọrọ aforiji, ki gbogbo ọrọ naa si pari sibẹ. Ṣugbọn kaka bẹẹ, wọn yoo ma sọ isọkusọ, wọn yoo si tun maa da kun iṣoro baba naa ni. Wọn ni Tinubu ri Ọọni fin, awọn kan ni oun lo fi i jọba; awọn kan ni o ti mọ ọn tẹlẹ, o maa n fun un lowo, o si maa n gbe iṣẹ fun un; awọn kan ni Ọọni lo ti fi ara ẹ wọlẹ niwaju ẹ, eeyan daadaa ni Tinubu. Laakaye awọn eleyii ko sọ fun wọ pe ki i ṣe Ọọni ni Tinubu ta abuku fun, pe gbogbo Yoruba ni. Laakaye wọn ko sọ fun wọn pe oloṣelu kan ko lẹtọọ lati fi aṣa ati iṣe wa wọlẹ, ọpọlọ wọn ko si sọ fun wọn pe bayii kọ ni Tinubu n ṣe si wọn nilẹ ajoji, ibi yii nikan naa ni arifin ati akọ ẹlẹsinrin bayii ti mọ. Oore gidi ni awọn ti wọn fẹran Tinubu yoo ṣe fun ara wọn, ati fun gbogbo ilu lapapọ bi wọn ba le duro niwaju rẹ, ki wọn maa ba a sọ ootọ ọrọ, ṣugbọn iru eyi ti wọn n ṣe yii, Ọlọrun ma jẹ ko jẹ funra wọn ni wọn yoo ti ọkunrin naa pa.

 

Kin ni wahala Fayoṣe bayii o

Ofin wa ninu gbogbo ẹgbẹ oṣelu, ofin naa si ni pe ẹni yoowu to ba di ipo to ga ju lo mu ni ipinlẹ kan tabi lọdọ ijọba apapọ ni yoo maa ṣe olori ẹgbẹ naa pata ni ipinlẹ wọn. Eyi ni pe bi gomina ba wa ni ipinlẹ kan, oun ni yoo jẹ olori pata fun ẹgbẹ oṣelu rẹ. Bi wọn ko ba ni gomina, ti wọn ba ni aṣofin nile-igbimo aṣofin apapọ, iru ẹni bẹẹ ni yoo jẹ olori fun ẹgbẹ oṣelu rẹ ni ipinlẹ to ti wa. Nigba ti Ayọdele Fayoṣe jẹ gomina ni ipinlẹ wọn, oun ni olori PDP nibẹ, ko si ẹnikan to ba a du ipo naa, kaluku lo si foribalẹ fun un. Nigba ti Fayoṣe fi ipo gomina silẹ, ọkunrin naa ko fẹẹ fi ipo olori ẹgbẹ PDP ipinlẹ rẹ silẹ,o taku, o n ba ẹni to jẹ ọmọ ileegbimọ aṣofin apapọ, Biọdun Olujimi, ja, ko si fẹẹ ṣe ọmọlẹyin fun iyẹn, o ni oun ni baba gbogbo wọn. O ko awọn kan jọ, awọn yẹn ni awọn n mulẹ, awọn dindinrin, wọn n bura iku ojiji funra wọn nitori Fayoṣe. Nitori kin ni ọkunrin yii ṣe n ṣe gbogbo eleyii! Gomina ipinlẹ Ọyọ, gomina kan ṣoṣo ti PDP ni ni ilẹ Yoruba, eyi to sọ ọ di olori ẹgbẹ naa ni ilẹ Yoruba yii, loun yoo wa si Ekiti lati waa ba wọn yanju ọrọ, Fayoṣe ni ko ma da si ọrọ awọn. Ta lo waa fẹẹ da si i. Ohun ti ko ṣe fẹ ki ẹnikẹni da si i naa ni pe o ti mọ pe nigba ti wọn ba ro ẹjọ yii kalẹ, afi ẹni ti ko ba fẹẹ ṣe ootọ, oun ni wọn yoo da lebi, nitori oun lo ṣe asiko tirẹ tan ti ko fẹ kẹlomi-in ṣe, oun ni ko jẹ ki alaye ṣe aye ẹ. Bo ba tiẹ jẹ pe ẹgbẹ gidi lo n tori ẹ ṣe eyi, wọn yoo ni nitori ohun to wa nibẹ ni, PDP ti ẹsẹ rẹ ti fẹẹ tan nilẹ l’Ekiti, kaka ki Fayoṣe si ba awọn to ku fọwọsowọpọ ki wọn tun ẹgbẹ naa ṣe, ija agba lo n ja, o si daju pe yoo lu ẹgbẹ naa fọ kia. Ohun to si ṣẹlẹ naa ko ju pe awọn eeyan yii ki i niṣẹ gidi kan ti wọn yoo pada si ti wọn ba ti fi ipo oṣelu silẹ, wọn yoo maa rin kiri bii igbona ni! Abi kin ni iṣẹ Fayoṣe bayii o! Wọn ki i ronu anfaani ti wọn le fi iriri wọn ti wọn ni nile ijọba ṣe fun araalu, bi wọn yoo ṣe tun ri ipo oṣelu mi-in ni wọn yoo maa le kiri. Gbogbo ẹ naa si ree, aajo ole ni, aajo ẹnu ni, nitori nidii oṣelu ole ti wọn n ṣe yii ni wọn yoo ti ri owo ti wọn ko le ri nidii iṣẹ yoowu laelae, nibẹ ni wọn yoo ti ri owo ti ẹni to n fi gbogbo ọjọ aye rẹ ṣiṣẹ gidi ko ni i ri ti yoo fi ku. Ohun ti wọn ṣe n fẹẹ para wọn ree. Awọn ara Ekiti yoo ṣaa si ti mọ bayii pe ki i ṣe nitori ifẹ tiwọn ni Fayoṣe ṣe n ba awọn elẹgbẹ rẹ ja ninu PDP, nitori ifẹ tara rẹ nikan ni. Ko mura si  i o, nigba ti wọn ba jọ lu ẹgbẹ naa fọ, a oo tun maa wo ibi ti yoo sa gba lọ.

 

Ina to jo nile awọn eleto-idibo l’Ondo

Eto idibo to n bọ ni ipinlẹ Ondo yii, ọwọ Ọlọrun ni yoo wa. Ohun ti yoo si fa a naa ni pe imura ti awọn oloṣelu ipinlẹ naa n mu, koda, o ju ti awọn ti wọn fẹẹ dibo aarẹ ni orilẹ-ede kan lọ. Bẹẹ  ọpọlọpọ imura yii ni ki i ṣe imura daadaa, imura ijamba ni, ki Ọlọrun ko awọn eeyan ibẹ yọ ni. Ibo ko ti i bẹrẹ, ileeṣẹ to n ṣeto idibo gbina, ina naa ko si ri ibi meji jo ju ibi ti wọn n ko maṣinni ti yoo ka kaadi ti wọn ba fi dibo si lọ. Awọn maṣinni yii ti bajẹ niyẹn, loootọ si ni ijọba ati awọn ti wọn n ṣeto ibo ni awọn yoo ko omi-in jade fun wọn, ọrọ naa dun lẹnu ni, ki i yaa bẹẹ, nitori ọpọ ohun ni wọn yoo ti fi kọmputa to sinu maṣinni to jona yii ti ko ni i ya lati tunṣe. O ṣee ṣe ko jẹ idi ti alaga ẹgbẹ PDP fi n pariwo pe ki awọn eeyan ma jẹ ki awọn APC fi ojooro ibo gbe ara wọn wọle ree, nitori bi kaadi yii ko ba ṣiṣẹ, ọwọ ni wọn yoo fi ka a, ohunkohun lo si le ṣẹlẹ nibi ti wọn ba ti n fi ọwọ lasan ka’bo, iye nọmba to ba wu wọn ni wọn yoo kọ si i. Ṣugbọn bi PDP ti n pariwo naa ni APC n pariwo pe ki wọn ma jẹ kawọn PDP ṣojooro ibo, eyi daju pe awọn mejeeji lo mọ ohun ti awọn le ṣe. Ohun gbogbo to wa nibẹ ṣaa o, ọwo awọn ara ipinlẹ naa funra wọn lo wa, ti wọn ba ti mura lati fibo wọn gbe ẹni to wu wọn wọle, ti wọn jinna si owo abẹtẹlẹ, ti wọn ko gba agolo irẹsi tabi ọpa ankara marun-un nitori ibo, o daju pe awọn ti wọn ba fẹẹ ṣojooro yoo ronu wọn wo ki wọn too ṣe e. Ohun to n jẹ ki wọn ri ojooro ṣe nibi kan ni nigba tawọn eeyan ibẹ ba ti gbowo, awọn naa ti lọwọ si biribiri lọjọ idibo niyi, wọn ko si ni i le pariwo bi nnkan ba n lo bi ko ṣe daa. Ẹ jẹ kawọn oloṣelu maa ba ọgbọn ati ete wọn lọ. Ẹyin ẹ ṣaa ma gbowo lọwọ wọn. Bi ẹ ko ba ti gbowo lọwọ wọn, ohun ti ẹyin araalu ba fẹ ni yoo ṣẹ.

 

Ki Makinde gbọ ohun tawọn ẹgbẹ ọlọdẹ n sọ o

Sunday Igboho, ọkan ninu awọn ajijagbara ni ipinlẹ Ọyọ sọ ọrọ kan laipẹ yii, nipa ọrọ awọn Amọtẹkun ni. O ni eto ti ijọba n ṣe lati ko awọn alakọwe, awọn to ti jade ni yunifasiti, ati awọn mi-in bii tiwọn nikan wọ inu ikọ Amọtẹkun yii ki i ṣe ohun to le ṣiṣẹ. O ni bo ba jẹ a fẹ ki Amọtẹkun yii jẹ ti Yoruba loootọ, ọgbọn Yoruba ni a oo fi gbe nnkan wa kalẹ, awọn ọdẹ ati awọn ọmọ Yoruba ti wọn mọ irin inu igbẹ tẹlẹ lo yẹ ki wọn ko jọ, awọn ni wọn le wọ inu igbo, ti wọn yoo si mọ ọna lati gba mu awọn oniṣẹ ibi to yi ilẹ Yoruba ka. Ọro naa yoo da bii pe ko ṣe pataki, bẹẹ ohun to ṣe pataki ju lọ ninu eto Amọtẹkun yii ni. Bi Igboho ti wi, bẹẹ naa ni Olori ẹgbẹ Ọdẹ Sọludẹrọ, Nureni Ajijọlaanọbi, naa sọ lọsẹ to kọja yii, to ni ijọba ipinlẹ Ọyọ ko tilẹ pe awọn ẹgbẹ ọdẹ si ohun ti wọn n ṣe. Eyi yoo buru diẹ, nitori gbogbo ohun tijọba n ṣe yii, ati iru Amọtẹkun ti wọn n royin yii, nilẹ Yoruba nibi, iṣẹ awọn ọdẹ ni. Eyi ki i ṣe ọgbọn akọwe, bẹẹ ni ki i ṣe pe ki wọn fi oṣu mẹfa kọ awọn ọmọ to jẹ airiṣẹ kan ṣe lo jẹ ki wọn fẹẹ ṣe Amọtẹkun, ki wọn waa ni awọn ti ni awọn ọmọ ogun. Bi ọrọ ba dija ninu igbẹ, wọn yoo maa pa awọn ọmọ yii ṣere ni, awọn mi-in yoo si sa pada pata ninu wọn nigba ti wọn ba ri ina tootọ, itiju nla ni eleyii yoo jẹ fun gbogbo Yoruba, paapaa nigba ti awọn ọmọ yii ko ni ibọn tabi ohun ija oloro, ti ko si sẹni ti yoo ṣe oogun fun wọn. Bawo ni wọn yoo ṣe koju Fulani to n gbe ibọn rin kaakiri. Ohun ti Makinde ṣe gbọdọ gbọ ohun ti awọn ọdẹ n sọ ree, ko pe wọn ko ba wọn sọrọ, ki wọn ko awọn ọdẹ rẹpẹtẹ sinu Amọtẹkun, ki wọn le fi ọna han awọn ti ki i ṣe ọmọ ọdẹ ninu awọn ti wọn ba gba. Iyẹn nikan kọ, ki Makinde gba awọn gomina to ku naa nimọran, ko jẹ ki wọn mọ pe ohun ti awọn gbọdọ ṣe niyẹn. Ọgbọn alakọwe nikan ko ni i gbe Amọtẹkun debi kan o, ọgbọn Yoruba nikan l’Amọtẹkun yoo fi le jagun ṣẹgun.

Leave a Reply