Olukọ ileewe giga meji lo wa ninu awọn ti EFCC mu fun jibiti l’Ọfa

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lọwọ ajọ to n gbogun tiwa jibiti, EFCC, tẹ awọn olukọ ileewe giga ti wọn ti n kẹkọọ nipa eto ilera, Kwara State College of Health Technology, to wa nilu Ọffa, Abdulahi Ọpaṣhọla ati Adebisi Ademọla, pẹlu awọn afurasi mejidinlọgbọn mi-in fẹsun jibiti ori ayelujara.

EFCC ṣàlàyé ninu atẹjade kan pe kaakiri ipinlẹ Kwara lọwọ ti tẹ wọn lẹyin tawọn araalu ta wọn lolobo. Koda, ajọ naa ni awọn ṣi n wa babalawo wọn to jẹ igi lẹyin ọgba wọn.

Lara awọn nnkan ti wọn ri gba lọwọ wọn ni oriṣiiriṣii ọkọ ayọkẹlẹ, awọn foonu olowo nla, awọn ẹrọ kọmputa alagbeeka atawọn nnkan mi-in.

Awọn afurasi yooku tọwọ tẹ ni: Kingsley Essien; Tobilọba Adenuga; Tọpẹ Ayọdele; Rasheed Mujib; Ọladipọ Ọpẹyẹmi; Saadu Muktar; Ọladẹjọ Hammed; Hammed Tọpẹ; Ameachi Umenyi, Salauden Adam ati Afọlabi Gafar.

Awọn mi-in tun ni: Ọladimeji Timi; Rẹmilẹkun Adeolu; Audu John; David Momodu; Abdulkareem Samad; Adebiyi Sodiq; Dawodu Olusọji; Yusuf Amọo; Kẹhinde Ọlarenwaju; Philip Mike, Ademọla Adebukọla; Adeniyi Ọlamilekan; Adeyẹmi Adedeji; Ajayi Teslem; Ọlawale Ọladayọ, Ọlasunkanmi Ọlawale ati Adeleke Damilọla.

 

 

Leave a Reply