Adewale Adeoye
‘’A maa foju Ọgbẹni Sunday, ẹni ọgbọn ọdun kan, to ṣedajọ atọwọda fun Hafsat Umar. Ijiya nla lo wa fẹni to ba ṣe irú nnkan to ṣe yii, nitori ofin ko faaye gba pe keeyan ṣedajọ lati ọwọ ara rẹ, paapaa ju lọ nipinlẹ Bauchi yii’.’
Eyi lọrọ to jade lẹnu Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Ahmed Mohamed Wakil, lori bi Sunday ṣe da kẹrosiini le obinrin kan ti wọn pe ni Umar lori, to sì tun kina bọ ọ lara nitori to fẹsun kan an pe, ajẹ ni.
ALAROYE gbọ pe ninu ọgba ile ti Sunday n gbe lagbegbe Rafin-Albasa, nijọba ibilẹ Bauchi, ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Ohun ta a gbọ ni pe Umar lo deede wọnu ọgba ile ti Sunday n gbe, to si sọ pe ọkan lara awọn ẹgbọn Sunday lo ran oun wa lati waa pa Sunday danu, ati pe oun ti ri oogun kan mọ igun ile ti Sunday n gbe.
Gbogbo akitiyan Sunday lati le Umar jade kuro ninu ọgba ile rẹ lo ja si pabo. Nigba to ya ni ọmọkunrin yii tun sọ fun Umar pe ko waa hu oogun to loun ri mọ’nu ile naa kuro, ṣugbọn Umar ko da a lohun rara. Igbe pe, ‘wọn ni ki n waa pa ẹ’ ni Umar n ke kaakiri inu ọgba ile naa, ti ko si gba lati jade kuro ninu ile Sunday.
Nigba tinu bi Sunday lo ba binu wọle lọ, to si gbe epo oyinbo kan jade ninu ile rẹ, o da a si Umar lara, lẹyin naa lo ṣana si i e lara, ti Umar sí n kigbe oro buruku, ko too di pe wọn ba a bu omi pana ọhun lara rẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinle naa, S.P Ahmed Mohamed Wakil, to fìdíi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lakooko to n ṣafihan awọn ọdaran tọwọ tẹ kaakiri ilu ọhun sọ pe gbara tawọn ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, lawọn ti tete lọọ fọwọ ofin mu Sunday nile rẹ, tawọn si ti gbe Umar lọ sí ọsibitu ijọba kan to wa lagbegbe ọhun fun itọju.
Alukoro ni loootọ lawọn kan jẹrìí pe Umar yii lo wọle tọ Sunday, to sì n ṣe bii ajẹ ninu ile naa, ṣugbọn ẹṣẹ tawọn ka si i lẹsẹ ni pe o ṣedajọ lọwọ ara rẹ, eyi ti ofin ko faaye gba rara, ti ijiyà sí wa fẹni to ba ṣe bẹẹ labẹ ofin ipinlẹ naa.
Ọ ni awọn maa foju Sunday bale-ẹjọ lẹyin tawọn ba ti pari iwadii awọn nipa ohun to ṣe yii.