Faith Adebola
Ireti awọn ọmọ orileede yii lati ki Aarẹ ilẹ Naijiria kaabọ pada lati orileede France, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa yii, gẹgẹ bi wọn ti ṣe kede rẹ tẹlẹ ko wa si imuuṣẹ mọ bayii. Baba naa ti tatare lati orileede France kọja si ilu London, ni United Kingdom, nibi ti wọn lo ti fẹẹ lọ ṣabẹwo idakọnkọ kan.
Atẹjade kan ti Oludamọran pataki si Tinubu lori awọn akanṣe iṣẹ, ibanisọrọ ati ọgbọn-inu, Ọgbẹni Dele Alake, fi lede lọsan-an ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa yii, lo fidi ọrọ yii mulẹ.
O sọ ninu atẹjade ọhun pe Tinubu ti pari ipade ilu to tori ẹ lọ sorileede France, nibi to ti ṣepade ọlọkan-o-jọkan pẹlu awọn olori orileede agbaye mi-in, bẹẹ lo kopa ninu apero ti Aarẹ ilẹ Faranse, Emmanuel Macron, gbe kalẹ, eyi to da lori ‘awọn ọna tuntun lati kaju eto iṣuna owo kari-aye.’
Apero naa mu ki Aarẹ Tinubu ba awọn ẹlẹgbẹ rẹ sọrọ lori bi eto iranwọ ati amojuto akanṣe yoo ṣe wa fawọn orileede ilẹ Afrika, bi wọn ṣe le fẹ ọrọ-aje ati okoowo agbaye loju si i, bẹẹ lo sọrọ nipa awọn nnkan amuṣọrọ orileede ati eto agbara, ko si ṣai mẹnu ba ipenija iṣẹ ati oṣi to n ba awọn orileede to ṣẹṣẹ n goke agba finra ati awọn ọna abayọ. Tinubu tun sọrọ lori ayipada oju-ọjọ, bi igba ati akoko ṣe n yi pada kari aye.
Bo ba jẹ pe ko si ayipada kankan ninu irinajo Aarẹ ni, ọsan ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa yii, lo yẹ ko pada wale, ṣugbọn ninu atẹjade ọhun, Alake ni aarẹ ko le wa si Naijiria bayii, o ti balẹ siluu London, o ni Tinubu ni awọn abẹwo kan to fẹẹ ṣe nibẹ, ọrọ ara Aarẹ lo si ba lọ, ki i ṣe tilu o.
Amọ wọn ni abẹwo naa ko le pẹ rara, orileede yii ni Aarẹ Tinubu yoo ti gbadun pọpọṣinṣin ọdun Ileya pẹlu awọn mọlẹbi rẹ, ọdun naa si ti wọle de, tori ẹ, wọn l’Aarẹ yoo pada de laipẹ jọjọ, bo tilẹ jẹ pe wọn o sọ ọjọ pato ti yoo jẹ.