Monisọla Saka
Tijatija, togun togun, lawọn ọdọ ilu kan nipinlẹ Anambra, fi ya wọ ile alaṣẹwo kan, ti wọn lawọn ọmọde ni wọn n lo lati fi ṣe owo nabi nibẹ, ti wọn si tun fẹsun kan wọn pe oriṣiiriṣii iwa ọdaran mi-in lo n waye nibẹ.
Niluu kan ti wọn n pe ni Oba, ijọba ibilẹ Guusu Idemili, nipinlẹ Anambra, lawọn ọdọ naa ti ko ara wọn sori ọkada, ti wọn n pariwo lọ bii pe wọn fẹẹ lọọ jagun. Laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii ni, wọn ya bo ibẹ.
Gẹgẹ bi iwadii ṣe fidi ẹ mulẹ, arabinrin kan ti wọn n pe ni Madam Ukwu Venze, ni wọn lo ni ile aṣẹwo yii, to si n dari ẹ.
Inu yara ọtọọtọ ni wọn maa n ko awọn ọmọ ti wọn n lọ bi ọgbọn, ti ọjọ ori wọn wa laarin ọmọ ọdun mẹtala si mejidinlogun yii si lati fi ṣiṣẹ buruku yii.
Lasiko ti wọn n fọrọ wa awọn ọmọ naa lẹnu wo, ọkan ninu wọn ṣalaye pe ajọsọ ti wa lori bi awọn ṣe n pin owo iṣẹ. O ni ninu yara ti wọn ti pese kalẹ yii ni onikaluku awọn maa n duro si lati da awọn onibaara awọn lohun, ati pe bi ọja ba ṣe ya si, tabi ti awọn ba ṣe mọ ọrọ-ajee ṣe si ni yoo sọ iye tawọn maa pa loojọ.
O ni o ti niye ti yoo wọ apo madaamu ninu iyekiye tawọn ba pa lojumọ.
Ọkan ninu awọn ọmọ naa ti wọn tun ba sọrọ sọ pe ọmọ ọdun mẹtala loun, ati pe Ukpo, nipinlẹ Anambra, loun ti wa.
Yatọ si iwa lilo ọmọ nilokulo ti wọn lo n ṣẹlẹ nibẹ, wọn tun fẹsun awọn iwa ọdaran mi-in bii gbigbe ati lilo egboogi oloro, tita ọmọ, to fi mọ fifi wọn ṣowo ẹru igbalode kan wọn nibẹ.
Ninu fidio ti wọn gbe sori ẹrọ ayelujara lori iṣẹlẹ yii, ko ti i sẹni to le sọ boya wọn ri iya to ni ile aṣẹwo naa mu. Bẹẹ ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, ko ti i sọ ohunkohun lori ọrọ yii.