Adigunjale ya wọ aafin ọba

Adeoye Adewale

Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Minna, nipinle Niger, ti ni awọn ti gbọ si iṣẹlẹ awọn adigunjale kan ti wọn lọọ kogun ja Emir tilu Minna, Alhaji Umar Farouk Bahago, ti wọn si ja a lole owo atawọn dukia rẹ.

Yatọ si pe awọn ole ọhun ji owo, wọn tun ṣe awọn ọdẹ inu agbala Emir ọhun leṣe gidi, ti wọn si wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun nileewosan ijọba kan to wa lagbegbe naa, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.

ALAROYE gbọ pe awọn adigunjale ọhun, ti iye wọn pọ daadaa, ni wọn tẹle ọkan lara awọn oṣiṣẹ Emir  to lọọ gba owo nla wa fun ọba naa. Bi ẹni ti wọn ran niṣẹ ṣe de sinu asfin naa pẹlu owo ọhun lawọn ole naa ti bẹrẹ si i yinbọn ọwọ wọn soke gbau-gbau lati fi da ipaya nla silẹ layiika ati agbegbe ibẹ. Iṣẹlẹ ọhun lo mu ki meji lara awọn ẹṣọ inu ọgba naa fara pa yanna-yanna.

Ọkan lara awọn oloye ọba yii tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye pe ko pẹ rara ti ẹni ti ọba ran niṣẹ pe ko lọọ gbowo waa foun de tawọn ole naa fi jade lati inu mọto kan ti wọn gbe wa, ti wọn si koju ija sawọn ẹṣọ  naa. Leyin tapa wọn ka wọn, nitori pe ọrọ naa ba wọn lojiji, ni wọn gba owo wọn ni ki wọn lọọ gba wa ni banki lọwọ wọn, ti wọn si sa lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlopaa ipinlẹ Niger, D.S.P Wasiu Abiọdun, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin, o si ṣeleri pe awọn maa too mu awọn ti won lọwọ si iṣẹ buruku naa. O fi kun un pe iṣẹ ti n lọ lọwọ bayii lati mu gbogbo wọn.

O waa rọ awọn eeyan agbegbe naa pe ki wọn fọwọ-sọwọ-pọ pẹlu awọn ọlọpaa lati le fọwọ ofin mu gbogbo awọn to ba lọwọ ninu iwa laabi ọhun.

 

Leave a Reply