Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Awọn jaguda meji kan, Esther Shehu ati David Kpanaki, ni awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ti fọwọ ofin mu, ti wọn si ti n ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn lori ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan awọn mejeeji pe wọn gbimọ-pọ lati lu ọkunrin kan, Alaaji Kamoru Yusuf, to ni ileeṣẹ Kam Steel, to wa lopopona Ajasẹ-Ipo, nipinlẹ naa, ni jibiti ẹgbẹrun lọna irinwo dọla ($400,000), lẹyin ti wọn parọ pe awọn fẹẹ ta ọkọ oju omi (vessel) fun un.
Agbefọba, ASP Yusuf Nasir, sọ fun ile-ẹjọ pe lọjọ kejidinlogun, oṣu Keje yii, ni Arakunrin kan, Tofa Ahmed, mu ẹsun wa si agọ ọlọpaa lorukọ Alaaji Kamoru Yusuf, pe ninu oṣu Keje, ọdun 2021, ni Ibrahim Shehu ati Jemima Shehu, ti wọn n wa bayii, ati David Kpanaki, ta ọkọ oju omi kan (vessel) lọna aitọ lorukọ ileeṣẹ kan ti wọn n pe ni PAZ Oil, fun olupẹjọ.
O ni afurasi akọkọ lo orukọ ọmọbinrin ẹni ọdun mẹrindinlogun kan gẹgẹ bii ọga agba ileeṣẹ naa, to si lo David Kpanaki, to jẹ ana rẹ gẹgẹ bii ọga agba keji lati fi lu olupẹjọ ni jibiti nipa tita ọkọ oju omi vessel fun un. Awọn ọlọpaa tọpasẹ wọn de agbegbe Gwarimpa, niluu Abuja, nibi tọwọ ti tẹ wọn.
Awọn afurasi mejeeji, Esther Shehu ati David Kpanaki, jẹwọ pe loootọ lawọn jẹbi ẹsun ọdaran ti wọn fi kan awọn.
Onidaajọ Ibrahim Muhammad, paṣẹ pe ki wọn lọọ ju awọn afurasi mejeeji sọgba ẹwọn titi ti oun yoo fi gba imọran lori ẹjọ naa. Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii.