Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahaman AbdulRazaq, ti gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣeto pinpin irẹsi fun awọn araalu.
Bakan naa lo ni awọn yoo tun pin agbado fun awọn agbẹ ọlọsin adiẹ atawọn to n sin ẹja.
L’Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹjọ yii, ni gomina sọrọ naa latẹnu Akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ nileejọba ipinlẹ naa, eyi to wa ni GRA, niluu Ilọrin. O ni awọn ti gba biliọnu meji ninu biliọnu mẹrin ti wọn fẹẹ fi pin paliétíìfù faraalu lati ọwọ ijọba apapọ, tawọn si fẹẹ fi owo ọhun ra irẹsi tawọn yoo pin fun gbogbo awọn ti ko rọwọ họri lasiko ti gbogbo nnkan di ọwọngogo yii latari owo iranwọ epo ti wọn yọ.
O ni lati le ri i pe ko si iyanjẹ, ẹlẹyamẹya tabi ẹlẹsinjẹsin ninu pipin irẹsi naa, awọn ti gbe igbimọ kalẹ lati ṣakoso rẹ. Lara awọn igbimọ naa ni Kọmisanna ọlọpaa ni Kwara, CP Ẹbunoluwarotimi Adelesi, Ẹmir ilu Shọ̀ǹgà, Dokita Haliru Yahya, aṣoju ẹgbẹ awọn Musulumi kan, Aalaga ẹgbẹ Jama’atu Nasrul Islam, Dokita Lawal Ọlọhungbẹbẹ, aṣoju ẹgbẹ Onigbagbọ kan, alaga ẹgbẹ ọmọ lẹyin Kristi (CAN), Arabinrin Grace Funkẹ, asoju ajọ DSS, aṣoju obinrin kan lati ọdọ ẹgbẹ awọn akanda ẹda, aṣoju ẹgbẹ akọroyin ni Kwara, Nigeria Union Of Journalists (NUJ) ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ajakaye fi kun un pe idi tawọn fi mu awọn eeyan yii sibi igbimọ ọhun ni pe awọn ni wọn sun mọ araalu, ti wọn si mọ awọn to yo ati awọn tebi n pa ti wọn nilo iranwọ.
Ni igunlẹ ọrọ rẹ, o ni ijọba ko ni pin irẹsi agolo kọọkan fun araalu o, ṣugbọn ti wọn ba gbe apo irẹsi fun ẹni kan ninu ile kan, ti ẹni naa wa n pin in ni agolo kọọkan fawọn alabaagbe rẹ, ko kan ijọba, ko si kan awọn to n pin irẹsi ọhun, nitori pe awọn araalu le maa lọ sori ayelujara ti wọn aa maa sọ pe irẹsi agolo kọọkan ni ijọba n pin gẹgẹ bii paliétíìfù.