Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbubọn lo sọrọ kan laipe yii, ohun ti baba naa si sọ ni pe o ṣe pataki ki awọn ileewe wa maa kọ awọn ọmọ lẹkọọ nipa ẹsin ilẹ Yoruba ki iwa ọmọluabi le pada si awujọ wa. Bi awọn ijọba wa ko ba ṣeto bi wọn yoo ti maa kọ awọn ọmọ ni ede, aṣa ati iṣe Yoruba, ohun gbogbo yoo tubọ maa baje si i ni.
Ẹlẹbuubọn sọrọ yii nibi ifilọlẹ ileewe kan to ṣẹṣẹ da silẹ, Ikin Tukun Comprehensive High School, ni Oke Baalẹ, l’Oṣogbo. O ni, ọna kan pataki ti a le fi dopin iwa ibajẹ lawujọ wa ni ki a bẹrẹ si i kọ awọn ọmọ lẹkọọ nipa ẹsin ati iwa ọmọluabi lawọn ile ẹkọ pamari ati girama.
Ifayẹmi sọ pe ẹkọ ẹsin Yoruba yoo wa ninu ohun ti wọn yoo maa kọ awọn ọmọleewe nileewe tuntun ọhun, bẹẹ ni wọn yoo tun ni imọ kikun nipa jijẹ ọmọluabi, ilodi si iwa ọlẹ, bi eniyan ṣe le ni ifarada ati bi a ṣe le jẹ oloootọ laarin awujọ.
Araba Awo ti waa rọ awọn ijọba ni gbogbo ipinlẹ Yoruba mẹfẹẹfa lati sọ kikọ ede Yoruba lawọn ileewe pamari ati girama di kan-an-npa kaakiri awọn ileewe nilẹ Yoruba. Bakan naa lo sọ pe, o ṣe pataki ki ẹkọ nipa Ifa olokun dohun ti wọn gbọdọ maa kọ nileewe lati fopin si idakuda ti awujọ da loni-in.
O ni oun da ileewe ọhun silẹ lati fi sami ayẹyẹ ọdun kẹwaa ti oun joye Araba Awo ti ilu Oṣogbo ni, ati pe afikun awọn ohun ti wọn yoo maa kọ nibẹ ni ẹkọ nipa Ifa, itan iṣẹdalẹ wa, bẹẹ gẹgẹ ni eto mọ-ọn-kọ mọ-ọn-ka naa yoo maa waye nibẹ bii awọn ileewe mi-in gbogbo.