Ibo ti wọn fẹẹ di ni ipinlẹ Ẹdo lọla ko wahala ba Tinubu

Boya Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lo fa wahala sọrun ara rẹ ni o, boya awọn oloṣelu si ni, ko seeyan to le sọ pato, ṣugbọn ohun to foju han gbangba bayii ni pe ọrọ ibo gomina ti wọn yoo di ni ipinlẹ Edo lọla ode yii ti ko wahala gidi ba a. Lọwọlọwọ bayii, awọn kan n leri lapa ibẹ pe ti awọn ba foju kan an nitosi awon, gbadogbado yoo gb’owo agbado lọwọ rẹ.

Ọla, Ọjọ Abamẹta, Satide ọjo kọkandinlogun oṣu yii, ni wọn yoo dibo lati yan gomina tuntun fun ipinlẹ Ẹdo. Aarin awọn meji ni ija naa si ti le ju: Godwin Ọbaseki to n ṣe gomina ibẹ lọwọlọwọ bayii, ati Pasitọ Osagie Ize-Iyamu. Ẹgbẹ oṣelu PDP lo fa Ọbasẹki kalẹ, nigba ti ẹgbẹ APC fa Ize-Iyamu kalẹ, ohun to si jẹ ki ọrọ naa le gan-an niyẹn. Idi ni pe ni ọdun mẹrin sẹyin (2016), awón mejeeji yii naa ni wọn jọ du ipo yii, ṣugbọn orukọ ẹgbẹ APC ni Ọbasẹki fi du ipo to si wọle bii gomina, nigba ti Ize-Iyamu du ipo naa lorukọ PDP ti ko wọle. Ṣugbọn ni bayii, ija de ninu APC, Ọbaseki kuro ninu nibẹ o gba PDP lọ, wọn si fa  a kalẹ ko waa du ipo gomina lẹẹkan si i. Bakan naa ni ija de ninu PDP, Ize Iyamu binu kuro o si gba APC lọ, wọn si tun fa oun naa kalẹ ko waa du ipo gomina lorukọ won lọdun yii.

Itumọ eyii ni pe ẹni to du ipo gomina lọdun mẹrin ṣeyin lorukọ PDP ni yoo du ipo ọhun lọdun yii lorukọ APC, ẹni to si du ipo naa lorukọ APC ni yoo du u lorukọ PDP, paṣipaarọ lasan ni. Ọrọ naa le gan-an ni, nitori Adams Oshiomhole ti i ṣe alaga APC ati gomina ipinlẹ Ẹdo yii tẹlẹ lo fa Ọbaseki kalẹ ni 2016 pe ko waa ṣe gomina, oun lo ṣe kampeeni fun un, to n bẹ awọn ara Edo pe ki wọn dibo fun un, nitori oun ko ri ẹni kan to le ṣejoba ipinlẹ Ẹdo daadaa bii Ọbasẹki. Koda, nigba naa, epe randu-randu lo n ṣẹ fun Ize-Iyamu, to ni ole ni, o fẹẹ waa ko owo awọn ara Ẹdo jẹ ni. Ṣugbọn ni ọdun yii, Oshiomhole yii kan naa lo fa Ize-Iyamu kalẹ, to si n dọbalẹ fun awọn ara Ẹdo pe misiteeki loun ṣe ni 2016 ti oun fa Ọbaseki kalẹ, Ize-Iyamu loun fẹ ki wọn ba oun dibo fun lọdun yii.

Ọrọ yi lo wa nilẹ ki Tinubu to o ki ori ara rẹ si i. Tinubu gbe fido kan jade ni, odidi fidio. Funrarẹ lo ṣe e, to si sọrọ nibẹ, gbogbo ohun to si sọ, eebu pata lo jẹ fun Ọbasẹki. O ni oun pe gbogbo ara Ẹdo ki wọn ma dibo fun Ọbasẹki, nitori lasiko ti awọn n ja ija ijọba tiwa-n-tiwa (dẹmokiresi) yii, Ọbasẹki ko ba awọn da si i rara. Ninu fidio naa lo ti sọ pe ọkunrin naa ko ni ibẹru ofin, o si n fabuku kan awọn ara Ẹdo, o ni gbogbo ẹni to ba fẹ daadaa ipinlẹ naa, ko jinna si Ọbasẹki. Nibi yii lo jọ pe Tinubu ti fori ja ile agbọn.

Lẹsẹkẹsẹ lawọn eeyan bẹrẹ si i sọ oriṣiriṣi ọrọ buruku ranṣẹ si ọkunrin oloṣelu nla yii, ti wọn ni ohun to kan an ninu ibo ti wọn fẹe di ni ipinlẹ Ẹdo ko ye awọn. Paripari rẹ si ni pe ki i ṣe awọn ara Ẹdo nikan ni wọn n sọ bẹẹ, kaakiri ilẹ Naijiria ni. Ohun to jọ pe o n dun awọn eeyan ju ni pe lọdun 2016, Tinubu yi naa wa ninu awọn ti wọn n mu Ọbaseki jade, ti wọn n jo kiri, ti won n sọrọ, oun naa si darin lọjọ ti wọn n ṣe kampeeni fun Ọbaseki yii, to ni oun ni ki gbogbo ara Edo dibo won fun. Ohun ti Ọbasẹki waa ṣe ̀lọdun yii, ti ko fi yẹ lẹni ti awon ara Ẹdo tun gbọdo sun mọ lawon eeyan naa n beere. Wọn ni ko si ohun meji to n ṣe Tinubu ju pe o n fẹ ẹni ti yoo tun maa gba owo awọn ara Ẹdo, ti yoo maa waa ko foun.

Tom Ikimi, ọkan ninu awon oloṣelu adugbo naa tilẹ jade, o ni mọto-agboworin ti Tinubu fi ge owo lọ si Eko lasiko ibo ti wọn di nibẹ lọdun to koja ko le ran awọn ni Ẹdo, pe nibi to ti n ko owo wọn na naa ni ko ti maa ko o, nigba to ba ya, wọn yo beere awọn owo naa lọwọ rẹ lọjọ kan, ṣugbọn ko ma gbe iru iwa palapala bẹe de Edo ṣaa. Koda, awọn ọmọ agbegbe naa kan ti ṣe ikilọ pe ti awọn ba ri Tinubu tabi ẹni to jọ ọ, tabi iranṣe rẹ kan lagbege Ẹdo yii, awon yoo jẹwọ ọmọ ọkọ fun un, pe ko yaa jokoo si Eko ẹ, ko gbọdo gba ibi kankan kọja lapa ọdọ awọn.

Awọn mi-in ko ri ohun to buru rara ninu nnkan ti Tinubu ṣe. Wọn ni asiko kampeeni ni, o si lẹtọọ, gẹgẹ bi aṣiwaju ẹgbẹ APC, lati polongo ibo fun ẹni ti ẹgbẹ wọn ba fa kalẹ, pe ti ko ba ṣe bẹẹ, a jẹ pe ki i ṣe aṣaaju rere niyẹn. Wọn ni bi gbogbo aṣaaju ẹgbẹ oṣelu lagbaaye ti n ṣe naa ni Tinubu se yii, awọn olóòrayè nikan ni won n bu u, bẹe ni ko si wahala ti ẹnikẹni le ko ba a.

Ọla ni wọn yoo dibo yii, nigba ti yoo ba si fi di irọlẹ ọjọ Aiku ti i ṣe Sannde, gbogbo eeyan ni yoo ti mọ, boya fidio ti Tinubu ṣe ṣiṣẹ tabi ko ṣiṣẹ.

One thought on “Ibo ti wọn fẹẹ di ni ipinlẹ Ẹdo lọla ko wahala ba Tinubu

Leave a Reply