Ọlawale Ajao, Ibadan
Nnkan ko ṣenuure fawọn oṣiṣẹ ajọ to n mojuto eto imọtoto ayika nipinlẹ Ọyọ pẹlu bi awọn tọọgi ṣe ya lu wọn, ti wọn si ṣe mẹta ninu wọn leṣee l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ niṣẹlẹ ọhun waye nigba tawọn ọmọ aye ya lu awọn oṣiṣẹ àjọ kólẹ̀-kódọ̀tí tawọn mi-in tun mọ si gbálùúmọ́ labẹ biriiji Mọlete to wa lẹgbẹẹ ile Oloye Lamidi Adedibu, agba oṣelu ilẹ Ibadan to ti ṣilẹ bora bii aṣọ.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, awọn ẹruuku ọhun ko sọ pe awọn ko lu awọn oṣiṣẹ ijọba naa pa bi kii baa ṣe pe awọn onitọhun tete ba ẹsẹ wọn sọrọ, ‘ẹni orí yọ, ó dilé’ ni wọn fawo ọrọ naa da ti wọn fi sa mọ awọn eeṣin-ò-kọkú ọmọ naa lọwọ.
Iya to jẹ awọn aṣoju ijọba yii ko ṣẹyin bi wọn ṣe n gbiyanju lati fidio awọn to n tapa si ofin ati ilana imọtoto ayika laduugbo naa.
Ṣaaju lawọn oṣiṣẹ ajọ yii ti fi imu awọn kọ̀lọ̀rànsí eeyan to n da idọti soju agbara lasiko ojo to n rọ lọwọ laaarọ ọjọ Tọsidee dánrin pẹlu bi ọwọ wọn ṣe tẹ mẹtala ninu wọn, ti wọn si sọ wọn satimọle.
Ọga ọlọpaa (to ti fẹyin ti) to jẹ alaga fun ajọ to n ri si pipa ofin imọtoto ayika mọ, ACP Francis Ojọmọ, fidi ẹ mulẹ pe meji ninu awọn eeyan wọnyi lọwọ kọkọ tẹ, nipasẹ wọn lọwọ si fi tẹ awọn mọkanla yooku, ki wọn too rọ gbogbo wọn da satimọle lẹyin ti wọn ti jẹbi ninu igbẹjọ oju ẹsẹ ti ijọba ipinlẹ Ọyọ gbe kalẹ fun iru awọn arufin bẹẹ.
ACP Ọjọmọ sọ pe o rọrun fun oun atawọn ọmo oun lati ri awọn to n dalẹ soju agbara lasiko tójò ba n rọ lọwọ mu nitori oun funra oun ti mọ ọpọlọpọ adugbo ti wọn ti n hu iru iwa ẹgbin bẹẹ kaakiri igboro Ibadan.