Amugbalẹgbẹẹ Akeredolu kọwe fipo silẹ, o gba inu ẹgbẹ ZLP lọ

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ 

Andrew Ogunṣakin, oludamọran agba fun Gomina Rotimi Akeredolu lori ọrọ oṣelu lẹkun Guusu ipinlẹ Ondo ti kọwe fipo silẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, ti eto idibo sipo gomina ku bii ọjọ mejilelogun pere.

Ọkunrin yii ni oun pinnu lati kọwe fipo silẹ nitori pe igbesẹ ti gomina ọhun n gbe lọwọ lodi si ifẹ inu awọn eeyan agbegbe ti oun ti wa.

Bo tilẹ jẹ pe Ogunṣakin ko darukọ inu ẹgbẹ oṣelu to fẹẹ lọ, sibẹ, ọna to fi ṣagbekalẹ lẹta yii fihan pe ko si ibomi-in to tun fẹẹ lọ ju inu ẹgbẹ ZLP lọ.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Igbẹjọ Timothy Adegoke: Adedoyin ṣepe fawọn oniroyin ni kootu

Florence Babaṣọla, Oṣogbo Iyalẹnu lo jẹ fawọn oniroyin laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, yii, nigba ti Dokita …

Leave a Reply

//zikroarg.com/4/4998019
%d bloggers like this: