Ọmọge ku mọ ọlọpaa lọwọ nibi ti wọn ti n ṣe ‘kinni’ lotẹẹli

Aderounmu Kazeem

Janto ni wọn gbe ọlọpaa kan, Sajẹnti Anthony Kachukwu, ju satimọle ni Suurulere, ti iwadii si bẹrẹ lori bi ọmọbinrin kan ṣe ku mọ ọn lọwọ lasiko ti wọn lọ ṣe kinni  lotẹẹli.

Laipẹ yii niṣẹlẹ ọhun waye lasiko ti Ṣajẹnti Anthony gbe ọrẹbirnin ẹ, Justina Omofuma, lọ si otẹẹli kan ti wọn pe orukọ e ni Exclusive Mansion Hotel ni Surulere l’Ekoo.

Ohun ta a gbọ ni pe, lati ọwọ aṣalẹ ni wọn ti jọ wọ ile itura ọhun lọ, ti awọn mejeeji si gbadun ara wọn daadaa titi di aarọ ọjọ keji. Bi ilẹ ti ṣe mọ bayii ni wahala de, ti nnkan si daru mọ ọlọpaa yii lọwọ.

Lẹyin ti ọmọbinrin naa ku mọ ọn lọwọ tan, alaye to ṣe ni pe, lojiji ni ọmọbinrin naa daku, to si ṣubu lulẹ. Ori to la mọlẹ yii ni wọn lo ṣokunfa iku ẹ lẹsẹkẹsẹ.

Ohun ta a gbọ ni pe, lasiko ti Anthony ati ọrẹbinrin ẹ yii n ba ara wọn sọrọ lọwọ niṣẹlẹ ọhun waye. Ọkunrin naa tiẹ sọ pe baluwẹ loun wa, nibi ti oun ti gbọ gbii lojiji, ki oloju si too sẹ ẹ, Justina ko gbọ ti araaye mọ.

Lojuẹsẹ ni Anthony ti fọrọ ọhun to agọ ọlọpaa to wa ni Surulere leti, ti wọn si ti ju oun naa si atimọle lati ṣewadii bọrọ ọhun ṣe jẹ gan an.

Lẹsẹkẹsẹ ni wọn ti gbe oku Justina lọ si Mainland Hospital fun ayẹwo lati mọ nnkan to ṣeku pa a.

Ṣa o, awọn mọlẹbi ẹ ti gba oku ẹ, wọn lawọn fẹẹ lọ sin in. Bakan naa ni wọn sọ pe awọn mọ ọkunrin ọlọpaa naa gẹgẹ bi ololufẹẹ Justina, awọn ko nilo iwadii tabi ṣe ẹjọ kankan.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa l’Ekoo, Ọgbẹni Olumuyiwa Adejọbi ti sọ pe, loootọ lawọn ẹbi ẹ ti ni ki awọn dawọ iwadii awọn duro lori iku to pa obinrin naa, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ṣi ni awọn ibeere kan ti awọn n bi Sajẹnti ọlọpaa naa, paapaa lori awọn ẹsun mi-in tawọn fi kan an.

 

Leave a Reply