Ile alaja mẹta da wo nileewe Excell College, Ejigbo

Faith Adebọla, Eko

Ọpẹ ni awọn eeyan n da lọdọ Ọlọrun pe ki i ṣe asiko ti awọn akẹkọọ wa nileewe niṣẹlẹ buruku to ṣẹlẹ, nibi ti ile alaja mẹta to wa nileewe girama kan ti wọn n pe ni Excell College, to wa niluu Ejigbo, nipinlẹ Eko, ti da wo lulẹ ni ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ṣẹlẹ. Ohun ti a n wi yii kọ ni a ba maa wi nitori iba ṣe akoba fun awọn akẹkọọ to ba wa ni yara ikawe yii lasiko naa.

Ile alaja mẹta naa to wa ni Ojule kẹẹẹdogun,  Ansarudeen, nibudokọ Ile-ẹpo, Iyana Ejigbo, niluu Eko, lo da wo lojiji ni nnkan bii aago mẹjọ kọja iṣẹju mẹẹẹdogun laaarọ ọjọ Abamẹta.

Abala meji ni ile yii ni, ti wọn si so pọ mọ ara wọn. A gbọ pe eyi to wo yii ti ṣakoba fun ekeji ti wọn jọ kọ papọ sẹgbẹẹ ara wọn ọhun.

ALAROYE gbọ pe ile naa ti n fun wọn ni amin pe o ti rẹ ẹ, bẹẹ ni awọn alaṣẹ ileewe naa ti n mura ati tun un ṣe ki iṣẹlẹ aburu naa too ṣẹlẹ.

Ileeṣẹ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko ti wa nibẹ lati daabo bo ẹmi awọn to wa nitosi ile naa.

Ohun ti inu ọpọ awọn to n gbe itosi iṣẹlẹ ọhun fi n dun, ti wọn si fi n dupẹ lọwọ Ọlọrun ni pe ki i ṣe asiko ti awọn ọmọleewe ti pada si ẹnu ẹkọ wọn ni eleyii ṣẹle, adanu nla ni iba mu wa.

Leave a Reply