Awọn ẹgbẹ kan ti wọn pera wọn ni Unity Forum, nipinlẹ Ọyọ, ti sọ pe ko so ootọ ninu ahesọ tawọn kan n gbe kiri pe awọn ti fọwọ si gomina ipinlẹ Ọyọ telẹ, Adebayọ Alao Akala, gẹgẹ bii aṣaaju ẹgbẹ APC nipinle Ọyọ. Ninu atẹjade kan tawọn aṣaaju ẹgbe ọhun mẹrẹẹrin ọhun , Senetọ Olufẹmi Lanlehin, Sẹnetọ Ayọ Adeṣeun, Senetọ Olusọji Akanbi ati Alaaji Adebayọ Shittu, fọwọ si ni wọn ti kede ọrọ naa. Wọn ni eleyii yatọ si ohun ti awọn fẹnu ko le lori nibi ipade kan tawọn ṣe pẹlu Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, ni ogunjọ, oṣu ta a wa yii.
Wọn ni loootọ ni Dokita Fayẹmi gba awọn nimọran lati gbe igbimọ awọn agbaagba ti yoo maa gba ẹgbẹ nimọran kalẹ, ti awọn kan si sọ pe ki awọn fi Alao Akala ṣe alaga igbimọ yii, ṣugbọn gbogbo awọn lawọn ta ko eleyii fun idi meji. Akọkọ ni pe ofin ẹgbẹ oṣelu APC ko faaye gba ẹni ti wọn le pe ni olori, iyẹn (Leader). Idi keji ni pe nitori iriri awọn adari ti awọn ti ni telẹ ti wọn n paṣẹ onikumọ, niṣe lo daa ki awọn kuku gbe igbimọ gbogbogboo silẹ, dipo ẹni ti yoo maa la le gbogbo ẹgbẹ lọwọ.
Ọpọlọpọ aewọn to wa nipade ni wọn tewọ gba aba yii gẹgẹ bi wọn ṣe wi, bẹẹ ni Alao Akala paapaa sọ ninu ọrọ ipari rẹ pe oun ko ṣetan lati jẹ alaga igbimọ kankan, adari ẹgbẹ naa loun feẹ jẹ.
Ohun ti wọn ni igbimọ naa fẹnu ko le lori ni pe ki Akala jẹ alaga igbimọ ti wọn gba lati da silẹ ọhun, ki wọn si mu awọn awọn igbakeji gomina meji to wa ninu ẹgbẹ naa, ati alaga ẹgbẹ APC, Akin Oke, gẹgẹ bii ọmọ igbimọ yii.
Awọn adari Unity Forum yii ni ko si idi fun ẹnikẹni lati maa waa kede pe wọn ti yan Akala gẹgẹ bii olori ẹgbe naa, bi ko ba ṣe pe awọn eeyan naa ni ero ati ja ẹgbẹ yii gba lọkan.