Aderounmu Kazeem
Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Kayọde Fayẹmi, ti sọ pe awada lasan ni awọn oloye ẹgbẹ oṣelu APC l’Ekiti ti wọn sọ pe awọn le oun danu ninu ẹgbẹ naa n ṣe.
Ana ọjọ Ẹti, Furaidee, ni iroyin ọhun jade pe wọn ti ni ki gomina yii ṣe gaaya diẹ fawọn ninu ẹgbẹ naa. Lara awọn oloye ẹgbẹ APC ti wọn ba awọn oniroyin sọrọ pe ki gomina naa lọọ gbele ẹ ni Sẹnetọ Fẹmi Ojudu atawọn mẹwaa mi-in lori ẹsun wi pe o ṣe atilẹyin fun Gomina Obaseki.
Ṣugbọn Ọgbẹni Yinka Oyebọde ti i ṣe akọwe feto iroyin ninu ijọba Fayẹmi ti sọrọ, o ni ofin wa daadaa ti ẹgbe oṣelu APC n tẹle , ati pe awọn eeyan kan ko le maa gọ sabẹ ika kan lati maa da ẹgbẹ ọhun ru, nipa ikede ti ko lẹsẹ nilẹ ti wọn n ṣe. Akọwe ijọba yii fi kun un pe, Dokita Kayọde Fayẹmi, ṣi ni olori ẹgbẹ naa l’Ekiti, ti mimi kan ko si le mi in.
Alaga ẹgbẹ naa l’Ekiti, Oloye Ọmọtọṣọ, ẹni ti akọwe ẹgbẹ oṣelu naa, Ade Ajayi, gbẹnusọ fun, sọ pe anfaani ṣi wa fawọn ti wọn tọwọ bọwe pe awọn le gomina ọhun kuro ninu ẹgbẹ lati sọ pe ko ri bẹẹ. N lawọn yen na aba taku, wọn ni k osi ohun t ojọ bẹe, afi ki Fayẹmi maa lọ.
Ṣugbọn awọn olori ẹgbẹ APC ni Abuja ti fagi le gbogbo eleyii o, wọn ni ki kaluku awọn ti wọn n ja yii sinmi jẹẹ, ati pe ko sẹni kan to laṣẹ tabi lẹtọọ lati le ẹnikẹni kuro ninu ẹgbẹ yii ninu wọn.