Adewale Adeoye
Ẹsẹ ko gbero ni kootu ajọ oṣiṣẹ, ‘National Industrial Court’, to wa niluu Abuja, ti i ṣe olu ilẹ wa, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, lasiko ti igbẹjọ n lọ lori ẹjọ tawọn oloye ẹgbẹ onimọto ‘National Union Of Road Transport Workers’ (NURTW), pe ara wọn.
Awọn agba ẹgbẹ onimọto meji kan ni wọn gbe ara wọn waa si kootu ọhun. Ohun ti wọn n beere fun ni pe ki Onidaajọ Abilẹkọ O.O Oyewunmi, ba wọn fẹsẹ ofin to ọrọ ọhun, kawọn le mọ ẹni to jẹ ojulowo aarẹ ẹgbẹ onimọto nilẹ wa laarin Oloye Tajudeen Baruwa ati Oloye Isa Ọrẹ, ti wọn jọ n ja sipo pataki ọhun lati nnkan bii oṣu bii meloo kan sẹyin.
ALAROYE gbọ pe lẹyin atotonu agbẹjọro awọn oloye ẹgbẹ mejeeji, adajọ sọ pe Oloye Tajudeen Baruwa ni ojulowo aarẹ ẹgbẹ onimọto (NURTW) ilẹ wa. O ni ojulowo ibo lawọn ọmọ ẹgbẹ onimọto ṣe lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023, nibi ti wọn ti kede pe Oloye Tajudeen Baruwa ni wọn yan sipo ọhun. O ni ojulowo ọmọ ẹgbẹ kaakiri isọri mẹfa ti wọn wa lorileede yii ni wọn peju-pesẹ sibi eto idibo ọhun, ati pe gbogbo ohun ti ofin ẹgbẹ onimọto ilẹ wa sọ pata ni wọn tẹle lasiko ti wọn n ṣeto idibo naa.
Bakan naa ni adajọ tun kilọ fun Oloye Najeem Yasin to ti figba kan jẹ aarẹ ẹgbe naa tẹlẹ pe ko yee da sọrọ iṣakooso ẹgbẹ naa mọ, nitori pe ki i ṣe oloye ẹgbẹ naa mọ. O ni loootọ, agba ẹgbẹ onimọto (NURTW) ni, ko lẹtọọ lati maa ṣe bii aarẹ tabi bakan nnu ẹgbẹ naa mọ.
Ninu idajọ ọhun ni Onidaajọ Oyewunmi ti bu ẹnu atẹ lu ibo awuruju tawọn ọmọ ẹgbẹ NURTW kan ṣe lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 to kọja yii, nibi ti wọn ti kede Oloye Isa Ọrẹ atawọn oloye rẹ gẹgẹ bii adele aarẹ, eyi ti ko ba ofin mu rara.
Adajọ tun ni ibo tawọn ọmọ ẹgbẹ onimọto NURTW ilẹ wa ṣe lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023, ni ‘Ta’ al Hotel’, to wa niluu Lafia, nipinlẹ Nasarawa, nibi ti wọn ti yan awọn oloye ẹgbẹ kan jẹ eyi to ba ofin ẹgbẹ naa mu, nitori pe ṣe ni wọn tẹle awọn ofin ẹgbẹ naa pata.
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 to kọja yii, ni Alhaji Musiliu Akinsanya, ẹni tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ, lọọ ko awọn ṣoja di olu ile ẹgbẹ awọn onimọto to wa lagbegbe Garki 2, niluu Abuja, lati pese aabo fun adele aarẹ ẹgbẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan.
Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹsan-an, ọdun to kọja, ni awọn ọlọpaa tun fọwọ ofin mu Baruwa, ti wọn si ju u sahaamọ wọn loju-ẹṣẹ.
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede wa lo da sọrọ naa ko too di pe wọn ju ọkunrin naa silẹ lahaamọ to wa. Latigba naa ni ẹjọ ọhun ti wa nile-ẹjọ, ko too di pe wọn ṣẹṣẹ da ẹjọ ọhun lọjọ kọkanla, oṣu yii.