Ọlawale Ajao, Ibadan
Ko ni i ṣee ṣe fawọn gomina ipinlẹ Ọyó lati maa yan ẹni to ba wu wọn sipo awọn alaga kansu mọ bayii. Alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ, Aarẹ Isiaka Abiọla Ọlagunju, lo sọrọ akinkanju yii lasiko abẹwo to ṣe si ileeṣẹ redio ijọba ipinlẹ Ọyọ, laduugbo Baṣọrun, n’Ibadan, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala, oṣu kẹta, ọdun 2024 yii.
Aarẹ Ọlagunju, to tun jẹ amofin-agba nilẹ yii (SAN), ṣapejuwe bi ọpọ awọn gomina lorileede yii ṣe maa n yan ẹni to ba wu wọn sipo alaga ijọba ibilẹ gẹgẹ bii ohun ti ko bofin ijọba awa-ara-wa mu.
O ni ohun to ba ofin ati ilana ijọba awa-ara-wa mu ni ki gbogbo ilu yan alaga kansu atawọn alakooso ijọba gbogbo sipo nipasẹ ibo didi.
Nigba to sọrọ lori idibo ijọba ibilẹ ti yoo waye jake-jado ìjọba ibilẹ mẹtẹẹtalelọgbọn (33) to wa nipinlẹ naa, alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ fi da gbogbo aye loju pe ẹni gbogbo ti awọn araalu ba dibo fun ju lọ lọjọ naa loun yoo kede gẹgẹ bii alaga kansu ati kansilọ agbegbe koowa wọn, nitori oun ko ni i faaye silẹ fun magomago ninu idibo naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ki i ṣe ọrọ asọgbọnnu ta a ba sọ pe awọn eeyan ki i kọbi ara si idibo ijọba ibilẹ, idi niyẹn ta a ṣe ni lati maa ṣe itaniji fawọn eeyan lori idibo yii ni gbogbo igba.
“Afojusun wa ni ki idaji awọn to forukọsilẹ tiẹ kopa ninu eto idibo yii. A si fẹ ki gbogbo aye mọ pe asiko ka maa kọ esi idibo silẹ ṣaaju ọjọ idibo gẹgẹ bii igbagbọ awọn eeyan kan ti kọja lọ, ko si nnkan to jọ bẹẹ mọ lasiko yii.
Ninu ọrọ tiẹ, Ọgbẹni Dọtun Ọlaitan, to gba wọn Lalejo ṣeleri pe gbogbo ohun to ba wa ni ikapa ileeṣẹ naa ni awọn yoo lo lati ṣatilẹyin fun ajọ OYSIEC lati ṣaṣeyọri lori awọn afojusun rẹ rere naa.